Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

2 Tímótì 1:7​—“Ọlọ́run Kò Fún Wa Ní Ẹ̀mí Ìbẹ̀rù”

2 Tímótì 1:7​—“Ọlọ́run Kò Fún Wa Ní Ẹ̀mí Ìbẹ̀rù”

 “Nítorí Ọlọ́run kò fún wa ní ẹ̀mí ojo, àmọ́ ó fún wa ní ẹ̀mí agbára àti ti ìfẹ́ àti ti àròjinlẹ̀.”​—2 Tímótì 1:7, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Nitoripe Ọlọrun kò fun wa ni ẹmí ibẹru; bikoṣe ti agbara, ati ti ifẹ, ati ti inu ti o ye koro.”​—2 Tímótì 1:7, Bibeli Mimọ.

Ìtumọ̀ 2 Tímótì 1:7

 Ọlọ́run lè ran ẹnì kan lọ́wọ́ kó lè nígboyà láti ṣe ohun tó tọ́. Ọlọ́run ò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni jẹ́ “ojo,” ìyẹn ni pé kò fẹ́ kéèyàn máa bẹ̀rù débi tẹ́ni náà ò fi ní lè ṣe ohun táá múnú òun dùn.

 Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ànímọ́ mẹ́ta tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká ní ká lè borí ìbẹ̀rù, ká má sì ṣojo.

 “Agbára.” Ọjọ́ pẹ́ táwọn Kristẹni ti ń fìgboyà sin Ọlọ́run láìka pé wọ́n ń kojú ìṣòro tó lágbára, táwọn ọ̀tá sì ń ta kò wọ́n. Síbẹ̀, wọn ò jẹ́ káwọn ìṣòro yẹn mú kí wọ́n fà sẹ́yìn. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27) Kí ló ràn wọ́n lọ́wọ́? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ ohun tó mú kó ṣeé ṣe, ó ní: “Mo ní okun láti ṣe ohun gbogbo nípasẹ̀ ẹni tó ń fún mi lágbára.” (Fílípì 4:13) Ọlọ́run lè fún àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ ní “agbára tó kọjá ti ẹ̀dá” kí wọ́n lè borí ìṣòro èyíkéyìí tí wọ́n bá kojú.​—2 Kọ́ríńtì 4:7.

 “Ìfẹ́.” Tí Kristẹni kan bá nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run látọkàn wá, á ṣeé ṣe fún un láti dúró lórí ìpinnu ẹ̀ láti ṣe ohun tó tọ́. Bákan náà, tí Kristẹni kan bá nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn dénú, ó máa múra tán láti fi àwọn nǹkan kan du ara ẹ̀ kó lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́, kódà tíyẹn bá máa mú kó fi ẹ̀mí ara ẹ̀ sínú ewu tàbí tó bá máa mú káwọn èèyàn ta kò ó.​—Jòhánù 13:34; 15:13.

 “Àròjinlẹ̀.” Nínú Bíbélì, ohun tó túmọ̀ sí láti ní àròjinlẹ̀ ni pé kí Kristẹni kan mọ béèyàn ṣe ń ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì kó lè ṣe ìpinnu tó tọ́. Ẹni tó bá láròjinlẹ̀ máa ń ro ọ̀rọ̀ síwá sẹ́yìn, á sì ronú dáadáa kó tó ṣèpinnu, kódà nígbà tí nǹkan bá nira. Ìpinnu tírú ẹni bẹ́ẹ̀ bá ṣe máa fi hàn pé ó fara mọ́ ohun tí Ọlọ́run fẹ́, torí ó gbà pé àjọṣe ohun pẹ̀lú Ọlọ́run ṣe pàtàkì ju èrò àwọn èèyàn lórí ọ̀rọ̀ kan.

Àwọn Ẹsẹ Tó Ṣáájú Àtèyí Tó Tẹ̀ Lé 2 Tímótì 1:7

 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ló kọ ìwé Bíbélì yìí, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Tímótì ló sì kọ ọ́ sí. Ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ làwọn méjèèjì, iṣẹ́ ajíhìnrere ni wọ́n sì jọ ń ṣe. Nínú lẹ́tà náà, Pọ́ọ̀lù fún ọ̀dọ́kùnrin yìí níṣìírí pé kó túbọ̀ máa lo gbogbo okun rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run. (2 Tímótì 1:1, 2) Ó ṣeé ṣe kí Tímótì jẹ́ ẹnì kan tó máa ń tijú, ìyẹn sì lè mú kó máa fà sẹ́yìn láti ṣe ojúṣe ẹ̀ nínú ìjọ. (1 Tímótì 4:12) Àmọ́ Pọ́ọ̀lù rán Tímótì létí pé Ọlọ́run fún un ní ẹ̀bùn kan, ìyẹn iṣẹ́ pàtàkì tó ní láti ṣe nínú ìjọ. Ó wá gbà á níyànjú pé kó máa lo àṣẹ tó ní láti bójú tó àwọn ará nínú ìjọ, kó máa fìtara wàásù, kó sì ṣe tán láti jìyà nítorí ìhìn rere.​—2 Tímótì 1:6-8.

 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Tímótì ni Pọ́ọ̀lù dìídì kọ ìwé náà sí, ó wúlò fún gbogbo àwọn tó bá fẹ́ sin Ọlọ́run tọkàntọkàn lónìí. Ó jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè sin òun lọ́nà tó tọ́, ká sì borí ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú.