ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ
Jẹ́nẹ́sísì 1:1—“Ní Ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run Dá Ọ̀run àti Ayé”
“Ní ìbẹ̀rẹ̀, Ọlọ́run dá ọ̀run àti ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:1, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
“ Ní àtètèkọ́ṣe Ọlọ́run dá ọ̀run òun ayé.”—Jẹ́nẹ́sísì 1:1, Bíbélì King James Version.
Ìtumọ̀ Jẹ́nẹ́sísì 1:1
Gbólóhùn tó bẹ̀rẹ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí sọ òtítọ́ pàtàkì méjì kan. Àkọ́kọ́ ni pé “ọ̀run àti ayé,” tàbí ayé, ọ̀run, òṣùpá, oòrùn àtàwọn ìràwọ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀. Ìkejì ni pé Ọlọ́run ló dá wọn.—Ìfihàn 4:11.
Bíbélì ò sọ bó ṣe pẹ́ tó tí Ọlọ́run ti dá ayé àtọ̀run, kò sì ṣàlàyé bó ṣe dá a. Ṣùgbọ́n, ó ṣàlàyé pé ‘okun tó pọ̀ yanturu tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́ àti agbára rẹ̀ tó ń bani lẹ́rù’ ló fi dá ayé.—Àìsáyà 40:26.
Ọ̀rọ̀ náà “dá” wá látinú ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù tá a fi ń ṣàlàyé ohun tí Ọlọ́run nìkan ṣoṣo bá ṣe. a Jèhófà b Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ni Bíbélì pè ní Ẹlẹ́dàá.—Àìsáyà 42:5; 45:18.
Kókó pàtàkì nípa Jẹ́nẹ́sísì 1:1
Ẹsẹ àkọ́kọ́ nínú ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣàlàyé bí Ọlọ́run ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í dá àwọn nǹkan bó ṣe wà nínú Jẹ́nẹ́sísì orí kìíní àti orí kejì. Láti Jẹ́nẹ́sísì 1:1 sí 2:4, Bíbélì sọ̀rọ̀ ṣókí nípa ohun tí Ọlọ́run ṣe nígbà tó ń dá ayé àti gbogbo ẹ̀dá alààyè tó wà nínú rẹ̀, tó fi mọ́ ọkùnrin àti obìnrin àkọ́kọ́. Lẹ́yìn èyí, Bíbélì wá ṣe kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí Ọlọ́run ṣe dá ọkùnrin àti obìnrin.—Jẹ́nẹ́sísì 2:7-25.
Ìwé Jẹ́nẹ́sísì ṣàlàyé pé ó lé ní “ọjọ́” mẹ́fà tí Ọlọ́run fi dá gbogbo ohun tó dá. Àwọn ọjọ́ náà kì í ṣe ọjọ́ oníwákàtí mẹ́rìnlélógún (24), a ò sì mọ bí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ṣe gùn tó. Nígbà míì, “ọjọ́” tiẹ̀ lè tọ́ka sí àkókò tó gùn ju wákàtí mẹ́rìnlélógún lọ. A rí èyí nínú Jẹ́nẹ́sísì 2:4, níbẹ̀ Bíbélì lo “ọjọ́” láti dúró fún “àkókò,” ó sì sọ pé gbogbo nǹkan tí Ọlọ́run dá fún ọjọ́ mẹ́fà àkọ́kọ́ dà bíi pé ó ṣẹlẹ̀ ní “ọjọ́” kan.
Èrò tí kò tọ́ nípa Jẹ́nẹ́sísì 1:1
Èrò tí kò tọ́: Ọlọ́run dá ọ̀run, ayé, òṣùpá, oòrùn àtàwọn ìràwọ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún mélòó kan sẹ́yìn.
Òtítọ́: Bíbélì ò sọ ìgbà tí Ọlọ́run dá ayé àtọ̀run. Gbólóhùn tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:1 kò ta ko ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì òde òní sọ pé ó ti tó ọ̀pọ̀ bílíọ̀nù ọdún tí ayé àtọ̀run ti wà. c
Èrò tí kò tọ́: Jẹ́nẹ́sísì 1:1 fi hàn pé Ọlọ́run jẹ́ Mẹ́talọ́kan torí pé ọ̀rọ̀ tó ń tọ́ka sí ẹni púpọ̀ ni èdè Hébérù lò fún “Ọlọ́run” nínú ẹsẹ yìí.
Òtítọ́: Èdè Hébérù náà ‘Elo·himʹ túmọ̀ sí “Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ tó ń tọ́ka sí ẹni púpọ̀ ni, ó sì máa ń jẹ́ ká rí bí ẹnì kan ṣe níyì tó tàbí bí ọlá rẹ̀ kò ṣe láfiwé, kì í ṣe iye èèyàn ló ń sọ. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ New Catholic Encyclopedia gbà pé ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ náà ‘Elo·himʹ tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì 1:1 “ń tọ́ka sí ẹnì kan, èyí sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ bíi wa táwọn ọba fi máa ń pọ́n ara wọn lé ló ń tọ́ka sí, kì í ṣe iye èèyàn.”—Ẹ̀dà Kejì, Apá 6, ojú ìwé 272.
Ka Jẹ́nẹ́sísì orí 1 àti àwọn àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé tí wọ́n fi ṣàlàyé ọ̀rọ̀ àti àwọn atọ́ka etí ìwé.
a Bíbélì HCSB Study Bible sọ nípa ọ̀rọ̀ náà pé: “Láwọn ibi tá a ti lo ọ̀rọ̀ ìṣe èdè Hébérù náà bara,’ tó túmọ̀ sí ‘láti dá,’ kì í tọ́ka sí ohun téèyàn ṣe. Torí náà ohun tí Ọlọ́run bá ṣe ní tààràtà ni bara’ máa ń tọ́ka sí.”—Ojú ìwé 7.
b Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.—Sáàmù 83:18.
c Nígbà tí ìwé The Expositor’s Bible Commentary ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tí ọ̀rọ̀ Hébérù tá a túmọ̀ sí “ní ìbẹ̀rẹ̀” ń tọ́ka sí, ó sọ pé: “Ọ̀rọ̀ náà ò sọ bí àkókò náà ṣe gùn tàbí bó ṣe pẹ́ tó.”—Ẹ̀dà Tí A Tún Ṣe, Apá I, ojú ìwé 51.