Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀLÀYÉ ÀWỌN ẸSẸ BÍBÉLÌ

Máàkù 11:24​—“Ohunkóhun Tí Ẹ Bá Béèrè fún Nínú Àdúrà, Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Pé, Ó Ti Tẹ̀ Yín Lọ́wọ́”

Máàkù 11:24​—“Ohunkóhun Tí Ẹ Bá Béèrè fún Nínú Àdúrà, Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Pé, Ó Ti Tẹ̀ Yín Lọ́wọ́”

 “Ìdí nìyí tí mo fi ń sọ fún yín pé, gbogbo ohun tí ẹ bá gbàdúrà fún, tí ẹ sì béèrè, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé ẹ ti rí i gbà, ó sì máa jẹ́ tiyín.”​—Máàkù 11:24, Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.

 “Torí náà, mo wí fún yín ohunkóhun tí ẹ bá béèrè fún nínú àdúrà, ẹ ní ìgbàgbọ́ pé, ó ti tẹ̀ yín lọ́wọ́, yóò sì jẹ́ tiyín.”​—Máàkù 11:24, Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Ìtumọ̀ Máàkù 11:24

 Àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni Jésù fi jẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ mọ̀ pé ó yẹ kí wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó lágbára pé àdúrà ń gbà. Ó jẹ́ kó dá wọn lójú pé kì í ṣe pé Ọlọ́run máa ń tẹ́tí sí àdúrà wọn nìkan, ó tún máa ń dáhùn ẹ̀. Ìyẹn ni pé, téèyàn bá ń gbàdúrà lọ́nà tó bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, ó yẹ kó dá a lójú pé Ọlọ́run máa ṣe é, tàbí kó kúkú gbà pé Ọlọ́run ti ṣe é.

 Jésù tẹnu mọ́ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó bá ń gbàdúrà. Ó sọ pé ẹni tó ń gbàdúrà kò gbọ́dọ̀ “ṣiyèméjì nínú ọkàn rẹ̀” àmọ́ kó “ní ìgbàgbọ́ pé ohun tí òun sọ máa rí bẹ́ẹ̀.” (Máàkù 11:23) Kí nìdí? Ìdí ni pé ẹni tó bá ń ṣiyèméjì kò ní “rí ohunkóhun gbà lọ́dọ̀ Jèhófà.” a​—Jémíìsì 1:5-8.

 Ẹni tó nígbàgbọ́ máa ń gbàdúrà nígbà gbogbo. (Lúùkù 11:9, 10; Róòmù 12:12) Èyí fi hàn pé ohun tó ń gbàdúrà fún ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, ó sì dá a lójú pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà rẹ̀. Bákan náà, ó gbà pé Ọlọ́run lè dáhùn àdúrà òun lọ́nà tó yàtọ̀ sí ohun tó ń retí àti lákòókò tó yàtọ̀.​—Éfésù 3:20; Hébérù 11:6.

 Àmọ́ o, ọ̀rọ̀ Jésù yìí kò túmọ̀ sí pé gbogbo nǹkan téèyàn bá béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run nínú àdúrà ló máa ṣe. Àwọn ọmọlẹ́yìn tó nígbàgbọ́, tí wọ́n sì ń ṣe gbogbo nǹkan tágbára wọn gbé nínú ìjọsìn Ọlọ́run ni Jésù ń bá sọ̀rọ̀. Bíbélì sọ pé Jèhófà máa ń tẹ́tí sí kìkì àwọn àdúrà tó bá ìfẹ́ rẹ̀ mu. (1 Jòhánù 5:14) Àmọ́, kì í tẹ́tí sí àdúrà àwọn tó ń mọ̀ọ́mọ̀ ṣàìgbọràn sí i àtàwọn tó kọ̀ láti ronú pìwà dà. (Àìsáyà 1:15; Míkà 3:4; Jòhánù 9:31) Tó o bá fẹ́ mọ sí i nípa àdúrà tí Ọlọ́run máa ń gbọ́, wo fídíò yìí.

Àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé Máàkù 11:24

 Láwọn ọjọ́ tí Jésù lò kẹ́yìn lórí ilẹ̀ ayé, ó lo àpèjúwe kan láti sọ ìdí tó fi ṣe pàtàkì kéèyàn ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. Bí wọ́n ti ń rìnrìn àjò lọ sí Jerúsálẹ́mù, Jésù kíyè sí igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tó ti rúwé. Àmọ́, torí pé Jésù ò rí èso kankan lórí igi náà, ó gégùn-ún fún un. (Máàkù 11:12-14) A lè fi bí ìrísí igi náà ṣe ń tanni jẹ ṣàpèjúwe bí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ṣe dà bíi pé wọ́n ń jọ́sìn Ọlọ́run àmọ́ tó jẹ́ pé wọn ò nígbàgbọ́. (Mátíù 21:43) Kò pẹ́ sí gbà yẹn ni igi ọ̀pọ̀tọ́ náà gbẹ, ìyẹn sì ń ṣàpẹẹrẹ ohun tó máa tó ṣẹlẹ̀ sí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìgbàgbọ́.​—Máàkù 11:19-21.

 Lọ́wọ́ kejì, ó dá Jésù lójú pé àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lè ní ìgbàgbọ́ tó lágbára débi tí wọ́n á fi borí àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní, kí wọ́n sì gbé àwọn nǹkan ribiribi ṣe lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run. (Máàkù 11:22, 23) Ìmọ̀ràn tí Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ àdúrà bọ́ sákòókò gan-an torí pé wọ́n máa tó kojú àwọn nǹkan tó máa dán ìgbàgbọ́ wọn wò. Bí àpẹẹrẹ, Jésù máa kú, ikú rẹ̀ sì máa dùn wọ́n gan-an. Kò tán síbẹ̀ o, àwọn alátakò tún máa fojú wọn rí màbo. (Lúùkù 24:17-20; Ìṣe 5:17, 18, 40) Bákan náà lónìí, táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù bá nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà wọn, ìyẹn á jẹ́ kí wọ́n lè borí àwọn ìṣòro tí wọ́n bá ní.​—Jémíìsì 2:26.

 Wo fídíò kékeré yìí kó o lè mọ ohun tó wà nínú ìwé Máàkù.

a Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run. (Sáàmù 83:18) Wo àpilẹ̀kọ náà “Ta Ni Jèhófà?