Lẹ́yìn Tí Jésù Jíǹde, Ṣé Ara Èèyàn Ló Ṣì Ní àbí Ó Ti Di Ẹ̀dá Ẹ̀mí?
Ohun tí Bíbélì sọ
Bíbélì sọ pé wọ́n pa Jésù ‘nínú ẹran ara, ṣùgbọ́n a sọ ọ́ di ààyè [jí i dìde] nínú ẹ̀mí.”—1 Pétérù 3:18; Ìṣe 13:34; 1 Kọ́ríńtì 15:45; 2 Kọ́ríńtì 5:16.
Ohun tí Jésù fúnra rẹ̀ sọ fi hàn pé ẹran ara kọ́ ló máa ní tó bá jíǹde. Ó ní òun máa ‘fi ẹran ara òun fúnni nítorí ìyè ayé,’ kó lè ra aráyé pa dà. (Jòhánù 6:51; Mátíù 20:28) Ká ní ẹran ara yẹn ló tún ní nígbà tó jíǹde ni, kò bá má lè rà wá pa dà. Ó dájú pé ohun tó ṣẹlẹ̀ kọ́ nìyẹn, torí Bíbélì sọ pé ó fi ara àti ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ rúbọ “lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún tún un ṣe mọ́ láé.”—Hébérù 9:11, 12.
Tó bá jẹ́ pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni Jésù nígbà tó jíǹde, báwo ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ṣe wá rí i?
Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí lè fara hàn bí èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn áńgẹ́lì kan ṣe bẹ́ẹ̀ láyé àtijọ́, wọ́n tiẹ̀ tún bá àwọn èèyàn jẹun. (Jẹ́nẹ́sísì 18:1-8; 19:1-3) Àmọ́ ẹ̀dá ẹ̀mí ṣì ni wọ́n, wọ́n sì lè pòórá.—Àwọn Onídàájọ́ 13:15-21.
Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, òun náà fara hàn bí èèyàn fúngbà díẹ̀, bí àwọn áńgẹ́lì ṣe máa ń ṣe. Torí pé ẹ̀dá ẹ̀mí ni, ó lè dédé yọ sí àwọn èèyàn tàbí kó pòórá lójijì. (Lúùkù 24:31; Jòhánù 20:19, 26) Ara tí Jésù máa ń ní láwọn ìgbà tó yọ sí àwọn èèyàn máa ń yàtọ̀ síra. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé àwọn ọ̀rẹ́ Jésù tímọ́tímọ́ gan-an ò tètè dá a mọ̀, ohun tó sọ tàbí ohun tó ṣe ni wọ́n fi dá a mọ̀.—Lúùkù 24:30, 31, 35; Jòhánù 20:14-16; 21:6, 7.
Ara tó ní àpá ọgbẹ́ ni Jésù fi fara han àpọ́sítélì Tọ́másì. Ó ṣe bẹ́ẹ̀ kó lè mú kí ìgbàgbọ́ Tọ́másì lágbára, torí Tọ́másì ò tètè gbà pé Jésù ti jíǹde.—Jòhánù 20:24-29.