Àwọn Wo Ló Ń Lọ sí Ọ̀run Àpáàdì?
Ohun tí Bíbélì sọ
Sàréè ni ọ̀run àpáàdì (“Ṣìọ́ọ̀lù” àti “Hédíìsì” látinú àwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì ní ìpilẹ̀ṣẹ̀) jẹ́, kì í ṣe ibi tí wọ́n ti ń dáni lóró. Àwọn wo ló máa ń lọ sí ọ̀run àpáàdì? Àwọn èèyàn rere àtàwọn èèyàn búburú. (Jóòbù 14:13; Sáàmù 9:17) Bíbélì sọ pé isà-òkú tí gbogbo ẹni tó bá kú ń lọ yìí ni “ilé ìpàdé fún gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.”—Jóòbù 30:23.
Kódà, Jésù gan-an lọ sí ọ̀run àpáàdì nígbà tó kú. Àmọ́, “a kò fi ọkan rẹ̀ silẹ̀ ni isà-òkú” torí Ọlọ́run jí i dìde.—Ìṣe 2:31, 32, Bibeli Yoruba Atọ́ka.
Ṣé títí láé ni àwọn èèyàn á fi máa wà ní ọ̀run àpáàdì?
Gbogbo àwọn tó bá lọ sí ọ̀run àpáàdì ló máa pa dà jíǹde, nígbà tí Jésù bá lo agbára tí Ọlọ́run fún un. (Jòhánù 5:28, 29; Ìṣe 24:15) Nígbà tí Bíbélì ń sọ̀rọ̀ nípa àjíǹde tó máa wáyé lọ́jọ́ iwájú, àsọtẹ́lẹ̀ tó wà nínú Ìṣípayá 20:13 sọ pé: “Ikú ati Isà-òkú si yọọda òkú ti o wa ninu wọn.” (Bibeli Yoruba Atọ́ka) Ọ̀run àpáàdì kò ní sí mọ́ tí kò bá ti sí àwọn òkú nínú sàréè mọ; ẹnì kankan kò ní lọ síbẹ̀ mọ́ tórí pé ‘ikú kì yóò sí mọ́.’—Ìṣípayá 21:3, 4; 20:14.
Àmọ́, kì í ṣe gbogbo àwọn tó kú ló lọ sí ọ̀run àpáàdì. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn èèyàn kan ti jingíri sínú ìwà búburú débi pé wọn ò lè ronú pìwà dà. (Hébérù 10:26, 27) Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá kú, inú Gẹ̀hẹ́nà tó ṣàpẹẹrẹ ìparun ayérayé ni wọ́n ń lọ, kì í ṣe ọ̀run àpáàdì. (Mátíù 5:29, 30) Bí àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé inú Gẹ̀hẹ́nà ni àwọn alágàbàgebè aṣáájú ìsìn tó wà nígbà ayé rẹ̀ ń lọ.—Mátíù 23:27-33.