Mò Ń Dá Ara Mi Lẹ́bi—Ṣé Bíbélì Lè Mú Kára Tù Mí?
Ohun Tí Bíbélì Sọ
Bẹ́ẹ̀ ni. Bíbélì lè mú ká ṣe ohun tó yẹ, ká má bàa dá ara wa lẹ́bi mọ́. (Sáàmù 32:1-5) Tá a bá ṣe ohun tí kò tọ́, àmọ́ tá a fi hàn pé ohun tá a ṣe yẹn dùn wá gan-an, Ọlọ́run máa dárí jì wá, á sì mú ká kọ́fẹ pa dà. (Sáàmù 86:5) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ó máa ń ṣàǹfààní nígbà míì tá a bá dá ara wa lẹ́bi torí pé ó lè mú ká fi ìwà tí kò tọ́ sílẹ̀, ká sì sapá láti yẹra fún irú ẹ̀ nígbà míì. (Sáàmù 51:17; Òwe 14:9) Àmọ́, Bíbélì rọ̀ wá pé ká má dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, ká má wo ara wa bí ẹni tí kò nírètí tàbí ẹni tí kò wúlò lójú Ọlọ́run. Tá a bá ń wo ara wa bẹ́ẹ̀, ‘ìbànújẹ́ lè bò wá mọ́lẹ̀.’—2 Kọ́ríńtì 2:7.
Kí ló lè mú kéèyàn máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi?
Ọ̀pọ̀ nǹkan ló lè mú kéèyàn máa dá ara ẹ̀ lẹ́bi. A lè kíyè sí i pé a ti ṣẹ ẹnì kan tá a fẹ́ràn tàbí ká má ṣe ohun tá a mọ̀ pé ó yẹ ká ṣe. Nígbà míì, a lè máa dá ara wa lẹ́bi kó sì jẹ́ pé a ò tiẹ̀ jẹ̀bi. Bí àpẹẹrẹ, tá a bá ṣòfin tó nira láti pa mọ́ fúnra wa, ó ṣeé ṣe ká bẹ̀rẹ̀ sí í dá ara wa lẹ́bi láìyẹ nígbà tá ò bá pa òfin náà mọ́. Ìdí nìyẹn tí Bíbélì fi rọ̀ wá pé ká má retí ohun tó pọ̀ jù lọ́wọ́ ara wa.—Oníwàásù 7:16.
Kí ni mo lè ṣe tí mi ò fi ní máa dá ara mi lẹ́bi mọ́?
Dípò tí wàá fi gbà pé ọ̀rọ̀ ẹ ti kọjá àtúnṣe torí àṣìṣe tó o ṣe, ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ kó o ṣe láti ṣàtúnṣe. Báwo lo ṣe lè ṣe é?
Gbà pé o ṣàṣìṣe. Tó o bá ń gbàdúrà, sọ fún Jèhófà a Ọlọ́run pé kó dárí jì ẹ́. (Sáàmù 38:18; Lúùkù 11:4) Ó dájú pé Ọlọ́run máa gbọ́ àdúrà ẹ tó o bá ronú pìwà dà, tó o fi hàn pé ohun tó o ṣe dùn ẹ́ gan-an, tó o sì sapá kó o má bàa ṣerú ẹ̀ mọ́. (2 Kíróníkà 33:13; Sáàmù 34:18) Òun nìkan ló mọ̀ wá dénú, ó sì mọrú ẹni tá a jẹ́. Tí Ọlọ́run bá kíyè sí i pé à ń sapá láti fi ìwà tí kò tọ́ sílẹ̀, ó máa dárí jì wá, “torí olóòótọ́ àti olódodo ni.”—1 Jòhánù 1:9; Òwe 28:13.
Tó o bá ṣẹ ẹnì kan, ó yẹ kó o gbà pé o ṣẹ ẹni náà, kó o sì bẹ̀ ẹ́ látọkàn wá. Ìyẹn lè má rọrùn! Ó gba pé kó o nígboyà, kó o sì jẹ́ onírẹ̀lẹ̀. Àmọ́, téèyàn bá tọrọ àforíjì látọkàn wá, ó máa ń jẹ́ kéèyàn lè ṣe àwọn nǹkan méjì pàtàkì yìí: Á jẹ́ kọ́kàn ẹ balẹ̀, àlàáfíà sì máa wà láàárín ìwọ àtẹni náà.—Mátíù 3:8; 5:23, 24.
Ronú lórí àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa bí Ọlọ́run ṣe ń fàánú hàn. Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí 1 Jòhánù 3:19, 20. Níbẹ̀, Bíbélì sọ pé ‘ọkàn wa lè dá wa lẹ́bi,’ ìyẹn ni pé, ká le koko mọ́ ara wa, kó máa ṣe wá bíi pé irú wa kọ́ ló yẹ kí Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́. Àmọ́, ẹsẹ yẹn tún sọ pé “Ọlọ́run ju ọkàn wa lọ.” Lọ́nà wo? Kò sóhun tí kò mọ̀ nípa wa, ó sì lóye bí nǹkan ṣe rí lára wa àtàwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa. Ó tún mọ̀ pé aláìpé ni wá, ìyẹn ni pé a ò lè ṣe ká má ṣàṣìṣe. b (Sáàmù 51:5) Nítorí náà, kì í pa àwọn tó bá kábàámọ̀ ẹ̀ṣẹ̀ wọn tì.—Sáàmù 32:5.
Yéé ronú lórí àwọn àṣìṣe rẹ. Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tó hùwà tí kò tọ́ àmọ́ tí wọ́n yí ìgbésí ayé wọn pa dà nígbà tó yá. Àpẹẹrẹ ẹnì kan ni Sọ́ọ̀lù ará Tásù, tá a wá mọ̀ sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Nígbà tó ṣì jẹ́ Farisí, ó ṣenúnibíni tó burú sáwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. (Ìṣe 8:3; 9:1, 2, 11) Àmọ́ nígbà tó mọ̀ pé Ọlọ́run àti Mèsáyà tàbí Kristi lòun ń ta kò, ó ronú pìwà dà, ó yí ìwà rẹ̀ pa dà, ó sì di Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù kábàámọ̀ ìwà tó hù, kò bẹ̀rẹ̀ sí í ronú lórí àwọn àṣìṣe rẹ̀. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù rí bí Ọlọ́run ṣe fàánú hàn sí òun, ó bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara wàásù, ìrètí àtiwà láàyè títí láé sì wà lọ́kàn ẹ̀.—Fílípì 3:13, 14.
Àwọn ẹsẹ Bíbélì tó sọ̀rọ̀ nípa dídá ara ẹni lẹ́bi àti ìdáríjì
Sáàmù 51:17: “Ìwọ Ọlọ́run, o kò ní pa ọkàn tó gbọgbẹ́ tó sì ní ìdààmú tì.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Ọlọ́run kò ní pa ọ́ tì torí àṣìṣe rẹ níwọ̀n ìgbà tó o bá gbà pé ohun tó o ṣe dun Ọlọ́run. Ó máa ń fàánú hàn.
Òwe 28:13: “Ẹni tó bá ń bo àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀ kò ní ṣàṣeyọrí, àmọ́ ẹni tó bá jẹ́wọ́, tó sì fi wọ́n sílẹ̀ la ó fi àánú hàn sí.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Tá a bá ṣẹ Ọlọ́run, tá a sì ṣàtúnṣe, ó máa dárí jì wá.
Jeremáyà 31:34: “Màá dárí àṣìṣe wọn jì wọ́n, mi ò sì ní rántí ẹ̀ṣẹ̀ wọn mọ́.”
Ohun tó túmọ̀ sí: Tí Ọlọ́run bá dárí jì wá, kò ní rán wa létí àwọn àṣìṣe wa mọ́. Ojúlówó àánú ló máa ń fi hàn.
a Jèhófà ni Orúkọ Ọlọ́run.—Ẹ́kísódù 6:3.
b Ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún látọ̀dọ̀ Ádámù, ọkùnrin àkọ́kọ́ ló mú kó máa wù wá láti ṣe ohun tí kò tọ́. Ádámù àti Éfà ìyàwó rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n pàdánù ìwàláàyè pípé tí wọ́n ní, àwọn ọmọ wọn náà sì di aláìpé.—Jẹ́nẹ́sísì 3:17-19; Róòmù 5:12.