Báwo Ni Mo Ṣe Lè Mọ Ìsìn Tòótọ́?
Ohun tí Bíbélì sọ
Nígbà tí Bíbélì ń ṣe àpèjúwe kan nípa bá a ṣe lè dá àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ mọ̀, ó sọ pé: “Àwọn èso wọn lẹ máa fi dá wọn mọ̀. Àwọn èèyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún, wọn kì í sì í kó ọ̀pọ̀tọ́ jọ láti ara òṣùṣú, àbí wọ́n máa ń ṣe bẹ́ẹ̀?” (Mátíù 7:16) Bí o ṣe lè fi ìyàtọ̀ sáàárín èso àjàrà àti igi ẹ̀gún, bẹ́ẹ̀ náà lo ṣe lè fi ìyàtọ̀ sáàárín ìsìn tòótọ́ àti ìsìn èké tó o bá wo ìwà àti ìṣe àwọn tó ń ṣe ìsìn náà. Díẹ̀ lára àwọn ohun tí a lè fi mọ ìsìn tòótọ́ nìyí.
Ìsìn tòótọ́ máa ń fi òtítọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kọ́ni, kì í kọ́ni ní ọgbọ́n orí èèyàn. (Jòhánù 4:24; 17:17) Lára àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ yìí ni òtítọ́ nípa ọkàn àti ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. (Sáàmù 37:29; Àísáyà 35:5, 6; Ìsíkíẹ́lì 18:4) Ìsìn tòótọ́ máa ń tú àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ èké tí àwọn onísìn fi ń kọ́ àwọn èèyàn.—Mátíù 15:9; 23:27, 28.
Ìsìn tòótọ́ máa ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run, ó sì ń jẹ́ kí wọ́n mọ orúkọ rẹ̀, ìyẹn Jèhófà. (Sáàmù 83:18; Àísáyà 42:8; Jòhánù 17:3, 6) Ìsìn tòótọ́ kì í kọ́ àwọn èèyàn pé Ọlọrun kò ṣeé sún mọ́ tàbí pé ó rorò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń kọni pé Ọlọ́run fẹ́ ká sún mọ́ òun.—Jémíìsì 4:8.
Ìsìn tòótọ́ máa ń kọ́ni pé nípasẹ̀ Jésù Kristi ni a fi lè rí ìgbàlà. (Ìṣe 4:10, 12) Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń pa àṣẹ Jésù mọ́, wọ́n sì máa ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.—Jòhánù 13:15; 15:14.
Ìsìn tòótọ́ gbà pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú gbogbo ìṣòro aráyé. Àwọn tó sì ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fìtara wàásù nípa Ìjọba yìí fún àwọn èèyàn.—Mátíù 10:7; 24:14.
Ìfẹ́ tó dénú máa ń wà láàárín àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́. (Jòhánù 13:35) Ìsìn tòótọ́ kọ́ni pé ká máa bọ̀wọ̀ fún àwọn èèyàn tó wá láti onírúurú ẹ̀yà, àṣà ìbílẹ̀ àti èdè. (Ìṣe 10:34, 35) Nítorí ìfẹ́ tí wọ́n ní síra wọn, wọn kì í lọ́wọ́ sí ogun jíjà.—Míkà 4:3; 1 Jòhánù 3:11, 12.
Ìsìn tòótọ́ kò ní àwọn olórí ìsìn tí wọ́n ń sanwó fún, bẹ́ẹ̀ sì ni wọn kì í fún ẹnikẹ́ni nínú ìjọ wọn ní àwọn oyè ńlá-ńlá.—Mátíù 23:8-12; 1 Pétérù 5:2, 3.
Ìsìn tòótọ́ kì í lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ òṣèlú rárá. (Jòhánù 17:16; 18:36) Àmọ́, àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń bọ̀wọ̀ fún ìjọba, wọ́n sì máa ń pa òfin ìjọba mọ́ ní ibikíbi tí wọ́n bá wà, ìyẹn sì bá ohun tí Bíbélì sọ mu pé: “Ẹ san àwọn ohun ti Késárì pa dà fún Késárì, [ìyẹn àwọn aláṣẹ] àmọ́ ẹ fi àwọn ohun ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”—Máàkù 12:17; Róòmù 13:1, 2.
Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fi ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣèwà hù. Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì ní gbogbo apá ìgbésí ayé wọn. (Éfésù 5:3-5; 1 Jòhánù 3:18) Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń fayọ̀ sin “Ọlọ́run aláyọ̀” láìka bí nǹkan ṣe lè le tó fún wọn.—1 Tímótì 1:11.
Àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ kì í pọ̀. (Mátíù 7:13, 14) Ìfẹ́ Ọlọ́run ni àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ máa ń ṣe, torí náà àwọn èèyàn kì í kà wọ́n sí, wọ́n máa ń fi wọ́n ṣẹ̀sín, wọ́n sì máa ń ṣe inúnibíni sí wọn.—Mátíù 5:10-12.
Ìsìn tòótọ́ kì í ṣe ‘ìsìn tó o bá ṣáà ti nífẹ̀ẹ́ sí’
Ó léwu téèyàn bá ń ṣe ìsìn kan torí pé ó kàn nífẹ̀ẹ́ sí i. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn èèyàn “á fi àwọn olùkọ́ [ìsìn] yí ara wọn ká, kí wọ́n lè máa sọ ohun tí wọ́n fẹ́ gbọ́.” (2 Tímótì 4:3) Àmọ́, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ṣe “ìjọsìn tó mọ́, tí kò sì ní ẹ̀gbin lójú Ọlọ́run àti Baba wa,” kódà tí ìsìn náà kò bá tiẹ̀ gbajúmọ̀.—Jémíìsì 1:27; Jòhánù 15:18, 19.