Orúkọ Àwọn Wo Ni Wọ́n Kọ Sínú “Ìwé Ìyè”?
Ohun tí Bíbélì sọ
Orúkọ àwọn èèyàn tó ń retí ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun ló wà nínú “ìwé ìyè” tí Bíbélì tún pè ní “àkájọ ìwé ìyè” tàbí “ìwé ìrántí.” (Ìṣípayá 3:5; 20:12; Málákì 3:16) Ọlọ́run ló ń pinnu àwọn tí orúkọ wọn á wọ inú ìwé ìyè, ìyẹn àwọn tó jẹ́ olóòótọ́ àti onígbọràn sí i.—Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 5:3.
Ọlọ́run kò gbàgbé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́, àfi bí ẹni pé ńṣe ló ti ń kọ orúkọ wọn sínú ìwé láti “ìgbà pípilẹ̀ ayé” wá. (Ìṣípayá 17:8) Ó jọ pé orúkọ ọkùnrin olóòótọ́ náà, Ébẹ́lì ló kọ́kọ́ wọ inú ìwé ìyè. (Hébérù 11:4) Kì í ṣe pé Ọlọ́run kàn ṣáà ń kọ orúkọ àwọn èèyàn bó ṣe wù ú, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni bó ṣe ń kọ orúkọ àwọn èèyàn sínú ìwé ìyè náà jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó “mọ àwọn tí í ṣe tirẹ̀” ni Jèhófà.—2 Tímótì 2:19; 1 Jòhánù 4:8.
Ǹjẹ́ Ọlọ́run lè pa àwọn orúkọ kan rẹ́ nínú “ìwé ìyè”?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run sọ nípa àwọn èèyàn aláìgbọràn tó wà ní orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì pé: “Ẹnì yòówù tí ó ti ṣẹ̀ mí, ni èmi yóò pa rẹ́ kúrò nínú ìwé mi.” (Ẹ́kísódù 32:33) Àmọ́, tí a bá jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run, orúkọ wa á ṣì máa wà nínú “àkájọ ìwé ìyè.”—Ìṣípayá 20:12.