Kí Ni Ẹ̀mí Mímọ́?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. (Míkà 3:8; Lúùkù 1:35) Ọlọ́run máa ń rán ẹ̀mí rẹ̀ jáde sí ibi tó bá wù láti fi mú kí ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Sáàmù 104:30; 139:7.
Inú ọ̀rọ̀ Hébérù kan tí wọ́n pè ní ruʹach àti ọ̀rọ̀ èdè Gíríìkì náà pneuʹma ni Bíbélì ti mú ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀mí” jáde. Ẹ̀mí mímọ́ ni ọ̀rọ̀ èdè Hébérù àti Gíríìkì yìí sábà máa ń tọ́ka sí lọ́pọ̀ ìgbà. (Jẹ́nẹ́sísì 1:2) Àmọ́, àwọn ọ̀nà míì tún wà tí Bíbélì gbà lo ọ̀rọ̀ náà, irú bí:
Èémí.—Hábákúkù 2:19; Ìṣípayá 13:15.
Afẹ́fẹ́.—Jẹ́nẹ́sísì 8:1; Jòhánù 3:8, Bíbélì Mímọ́.
Ẹ̀mí tàbí èémí tó ń síṣẹ́ nínú ẹ̀dá alààyè.—Jóòbù 34:14, 15.
Ìwà àti ìṣarasíhùwà èèyàn.—Númérì 14:24.
Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí, tó ní nínú Ọlọ́run àti àwọn áńgẹ́lì.—1 Àwọn Ọba 22:21; Jòhánù 4:24.
Àwọn nǹkan tí àwa èèyàn kò lè fojú rí ni gbogbo àwọn ohun tó wà lókè yìí, a sì gbà pé wọ́n wà. Bákan náà, ẹ̀mí mímọ́ “ò ṣeé fojú rí bí afẹ́fẹ́, kò ṣeé fọwọ́ kàn, ó sì lágbára.”—Ìwé An Expository Dictionary of New Testament Words, látọwọ́ W. E. Vine.
Bíbélì tún pe ẹ̀mí mímọ́ ní “ìka” tàbí “ọwọ́” Ọlọ́run. (Sáàmù 8:3; 19:1; Lúùkù 11:20; fi wé Mátíù 12:28.) Bí oníṣẹ́ ọnà kan ṣe máa ń fi ọwọ́ àti ìka rẹ̀ ṣe iṣẹ́, bẹ́ẹ̀ náà ni Ọlọ́run ṣe fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ṣe àwọn nǹkan yìí:
Àgbáálá ayé.—Sáàmù 33:6; Aísáyà 66:1, 2.
Bíbélì.—2 Pétérù 1:20, 21.
Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ayé àtijọ́ ṣe àti bí wọ́n ṣe fi ìtara wàásù.—Lúùkù 4:18; Ìṣe 1:8; 1 Kọ́ríńtì 12:4-11.
Ìwà dáadáa tí àwọn èèyàn Ọlọ́run ń hù.—Gálátíà 5:22, 23.
Ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan
Bí Bíbélì ṣe pe ẹ̀mí mímọ́ ní “ọwọ́,” “ìka” tàbí “èémí,” jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan. (Ẹ́kísódù 15:8, 10) Ọwọ́ oníṣẹ́ ọnà kò lè máa dá ṣiṣẹ́ lọ́tọ̀ láìsí ara àti ọpọlọ rẹ̀; bákan náà, ohun tí Ọlọ́run bá fẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ṣe ló máa ṣe. (Lúùkù 11:13) Bíbélì tún fi ẹ̀mí mímọ́ wé omi, ó sì fi hàn pé ó tan mọ́ àwọn nǹkan bí ìgbàgbọ́ àti ìmọ̀. Àwọn ìfiwéra tí Bíbélì ṣe yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀mí mímọ́ kì í ṣe ẹnì kan.—Aísáyà 44:3; Ìṣe 6:5; 2 Kọ́ríńtì 6:6.
Bíbélì sọ orúkọ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Ọmọ rẹ̀, Jésù Kristi fún wa, ṣùgbọ́n kò sí ibi tó tí sọ orúkọ ẹ̀mí mímọ́ fún wa. (Aísáyà 42:8; Lúùkù 1:31) Ẹni méjì ni Sítéfánù tó jẹ́ ajẹ́rìíkú rí nínú ìran tí Ọlọ́run fi hàn án, kì í ṣe ẹni mẹ́ta. Bíbélì sọ pé: “Bí ó [Sítéfánù] ti kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó tẹjú mọ́ ọ̀run, ó sì tajú kán rí ògo Ọlọ́run àti Jésù tí ó dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Ọlọ́run.” (Ìṣe 7:55) Ẹ̀mí mímọ́ tó jẹ́ agbára Ọlọ́run ló mú kí Sítéfánù rí ìran náà.
Àwọn àṣìlóye tí àwọn èèyàn ní nípa ẹ̀mí mímọ́
Àṣìlóye: Ẹnì kan ni “Ẹ̀mí” tàbí ẹ̀mí mímọ́, ó sì wà lára mẹ́talọ́kan bí 1 Jòhánù 5:7, 8 ṣe sọ nínú Bíbélì Mímọ́.
Òtítọ́: Nínú Bíbélì Mímọ́, ìwé 1 Jòhánù 5:7, 8 sọ pé: “ní ọ̀run, Baba, Ọ̀rọ̀, àti Ẹ̀mí Mímọ́: àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta yìí sì jẹ́ ọ̀kan. Àwọn mẹ́ta ní ó jẹ́rìí ní ayé.” Àmọ́, àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé kì í ṣe àpọ́sítélì Jòhánù ló kọ ọ̀rọ̀ tó wà nínú Bíbélì Mímọ́ tá a tọ́ka sí lókè yìí. Torí náà, kò yẹ kó wà nínú Bíbélì. Ọ̀jọ̀gbọ́n Bruce M. Metzger sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí kì í ṣe òótọ́, kò sì yẹ kó wà nínú Bíbélì Májẹ̀mú Tuntun.”—Ìwé A Textual Commentary on the Greek New Testament.
Àṣìlóye: Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́ bí i pé ẹnì kan ni, èyí sì fi hàn pé ẹnì kan ni.
Òtítọ́: Nígbà míì, Ìwé Mímọ́ máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀mí mímọ́ bí ẹni pé ó jẹ́ ẹnì kan, ṣùgbọ́n èyí kò fi hàn pé ó jẹ́ ẹnì kan. Kódà Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa ọgbọ́n, ikú àti ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni pé ẹnì kan ni wọ́n. (Òwe 1:20; Róòmù 5:17, 21) Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì sọ pé ọgbọ́n ní “àwọn iṣẹ́” àti “àwọn ọmọ.” Ó tún ṣe àpèjúwe ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni tó ń súnni dẹ́ṣẹ̀, tó ń pààyàn, tó sì ń ṣe ojúkòkòrò.—Mátíù 11:19; Lúùkù 7:35; Róòmù 7:8, 11.
Lọ́nà kan náà, nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń tọ́ka sí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, ó sọ̀rọ̀ ẹ̀mí mímọ́ bí ẹni pé ẹnì kan ni bó ṣe pè é ní “olùtùnú” (paraclete) tó máa fún wọn ní ẹ̀rí, ṣamọ̀nà, sọ̀rọ̀, gbọ́, polongo, yìn lógo àti gbà. Jòhánù lo àwọn ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ bíi “yóò” tàbí “ó” nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́ gẹ́gẹ́ bí “olùtùnú.” (Jòhánù 16:7-15) Àmọ́ ṣá o, ìdí tó fi lo àwọn ọ̀rọ̀ yìí ni pé ní èdè Gíríìkì, ọ̀rọ̀ orúkọ tí wọ́n máa ń lò fún ọkùnrin ni “olùtùnú” (pa·raʹkle·tos), ìlànà èdè yìí sì gba pé kí wọ́n lo ọ̀rọ̀ arọ́pò orúkọ tí wọ́n ń lò fún ọkùnrin níbi tí wọ́n bá ti lo irú ọ̀rọ̀ orúkọ yìí. Nígbà tí Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀mí mímọ́, ó lo ọ̀rọ̀ náà pneuʹma, tó jẹ́ ẹ̀dà ọ̀rọ̀ orúkọ míì tí wọn kì í lò fún ọkùnrin tàbí obìnrin, ìyẹn “rí i” àti “mọ̀ ọ́n.”—Jòhánù 14:16, 17.
Àṣìlóye: Bí Bíbélì ṣe sọ pé ká batisí àwọn èèyàn ní orúkọ ẹ̀mí mímọ́ fi hàn pé ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ ẹnì kan.
Òtítọ́: Bíbélì sábà máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “orúkọ” fún agbára tàbí ọlá àṣẹ. (Diutarónómì 18:5, 19-22; Ẹ́sítérì 8:10) Èyí sì bá bí wọ́n ṣe máa ń lò ó ní èdè Gẹ̀ẹ́sì mu. Bí àpẹẹrẹ, tí wọ́n bá sọ pé “ní orúkọ òfin,” kò túmọ̀ sí pé ẹnì kan ni òfin náà. Ẹni tí wọ́n bá batisí “ní orúkọ” ẹ̀mí mímọ́ gbà pé agbára Ọlọ́run ni ẹ̀mí mímọ́ àti pé òun ni Ọlọ́run ń lò láti fi mú ìfẹ́ rẹ̀ ṣẹ.—Mátíù 28:19.
Àṣìlóye: Àwọn àpọ́sítélì Jésù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ìgbàanì gbà pé ẹnì kan ni ẹ̀mí mímọ́.
Òtítọ́: Bíbélì kò sọ bẹ́ẹ̀, a kò sì rí i kà bẹ́ẹ̀ nínú ìtàn. Ìwé Encyclopædia Britannica sọ pé: “Inú àpérò Constantinople ní ọdún 381, ní ọjọ́ olúwa wa ni wọ́n ti sọ pé . . . ẹni mímọ́ tó dá yàtọ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ jẹ́.” Èyí wáyé lẹ́yìn àádọ́ta lérúgba [250] ọdún tí ẹni tó kẹ́yìn lára àwọn àpọ́sítélì kú.