Ṣé Ibi Gbogbo Ni Ọlọ́run Wà?
Ohun tí Bíbélì sọ
Ọlọ́run lè rí gbogbo nǹkan, ó sì lè ṣe ohun tó fẹ́ níbikíbi tó bá wù ú. (Òwe 15:3; Hébérù 4:13) Àmọ́, Bíbélì ò fi kọ́ni pé gbogbo ibi ni Ọlọ́run wà tàbí pé Ọlọ́run wà nínú ohun gbogbo. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni gidi kan ni Ọlọ́run, ó sì níbi tó ń gbé.
Bí Ọlọ́run ṣe rí: Ẹni ẹ̀mí ni Ọlọ́run. (Jòhánù 4:24) Àwa èèyàn ò lè rí i. (Jòhánù 1:18) Àwọn ìran tí Bíbélì sọ pé àwọn kan rí nípa Ọlọ́run máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní ibì kan pàtó tó wà. Wọn ò mẹ́nu bà á rí pé ibi gbogbo ló wà.—Aísáyà 6:1, 2; Ìṣípayá 4:2, 3, 8.
Ibi tí Ọlọ́run ń gbé: Ọ̀run ni Ọlọ́run ń gbé, níbi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí wà, ibẹ̀ sì yàtọ̀ sí ayé tàbí ojú ọ̀run tá à ń rí. Níbi táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yẹn wà, Ọlọ́run ní “ibi tí [ó] ń gbé, ní ọ̀run.” (1 Àwọn Ọba 8:30) Bíbélì sọ̀rọ̀ ìgbà kan táwọn ẹ̀dá ẹ̀mí “wọlé láti mú ìdúró wọn níwájú Jèhófà,” a ìyẹn jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ní ibì kan pàtó tó ń gbé.—Jóòbù 1:6.
Tí Ọlọ́run ò bá sí níbi gbogbo, ṣé ó wá lè rí tèmi rò?
Bẹ́ẹ̀ ni. Ọlọ́run mọ gbogbo wa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, ọ̀rọ̀ wa sì jẹ ẹ́ lógún gan-an. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀run ló ń gbé, Ọlọ́run máa ń rí àwọn tó fẹ́ ṣe ìfẹ́ rẹ̀ láyé, ó sì máa ń ràn wọ́n lọ́wọ́. (1 Àwọn Ọba 8:39; 2 Kíróníkà 16:9) Wo bí Jèhófà ṣe ń ran àwọn tó ń fi òótọ́ inú sìn ín lọ́wọ́:
Tó o bá gbàdúrà: Gbàrà tó o bá gbàdúrà sí Jèhófà ló lè gbọ́ ẹ.—2 Kíróníkà 18:31.
Tó o bá sorí kọ́: “Jèhófà sún mọ́ àwọn oníròbìnújẹ́ ní ọkàn-àyà; ó sì ń gba àwọn tí a wó ẹ̀mí wọn palẹ̀ là.”—Sáàmù 34:18.
Tó o bá ń wá ìtọ́sọ́nà: Jèhófà máa lo Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ láti ‘mú kí o ní ìjìnlẹ̀ òye, á sì fún ọ ní ìtọ́ni.’—Sáàmù 32:8.
Èrò tí kò tọ́ táwọn èèyàn ní pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà
Èrò tí kò tọ́: Ọlọ́run wà nínú gbogbo ohun tó dá.
Òótọ́: Kì í ṣe ayé ni Ọlọ́run ń gbé, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe inú àwọn ohun tó wà lójú ọ̀run. (1 Àwọn Ọba 8:27) Òótọ́ ni pé àwọn ìràwọ̀ àtàwọn ohun míì tí Ọlọ́run dá “ń polongo ògo Ọlọ́run.” (Sáàmù 19:1) Àmọ́ Ọlọ́run kì í gbé inú àwọn ohun tó dá. Bí àpẹẹrẹ, ayàwòrán kan ò lè máa gbé nínú àwòrán tó yà. Síbẹ̀, àwòrán náà lè jẹ́ ká mọ irú èèyàn tí ẹni tó yà á jẹ́. Lọ́nà kan náà, àwọn ohun tá à ń rí láyé jẹ́ ká mọ “àwọn ànímọ́ [Ẹlẹ́dàá] tí a kò lè rí,” bí agbára, ọgbọ́n àti ìfẹ́.—Róòmù 1:20.
Èrò tí kò tọ́: Tí Ọlọ́run ò bá sí níbi gbogbo, kò ní lè mọ gbogbo nǹkan, kó sì lè lágbára lórí ohun gbogbo.
Òótọ́: Ẹ̀mí mímọ́ ni agbára tí Ọlọ́run fi ń ṣiṣẹ́. Ọlọ́run lè fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ mọ ohunkóhun, ó sì lè fi ṣe ohunkóhun, níbikíbi, nígbàkigbà láìjẹ́ pé òun fúnra rẹ̀ wà níbẹ̀.—Sáàmù 139:7.
Èrò tí kò tọ́: Sáàmù 139:8 kọ́ wa pé ibi gbogbo ni Ọlọ́run wà, torí ó sọ pé: “Bí mo bá gòkè re ọ̀run, ibẹ̀ ni ìwọ yóò wà; bí mo bá sì ga àga ìrọ̀gbọ̀kú mi ní Ṣìọ́ọ̀lù, wò ó! ìwọ yóò wà níbẹ̀.”
Òótọ́: Kì í ṣe ibi tí Ọlọ́run wà ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí ń sọ. Ṣe ló ń sọ̀rọ̀ lówelówe pé kò síbi tó jìnnà jù fún Ọlọ́run láti dé kó lè ràn wá lọ́wọ́.
a Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.