Ṣé Bíbélì Ta Kora?
Ohun tí Bíbélì sọ
Rárá o, Bíbélì bára mu látìbẹ̀rẹ̀ dé ìparí. Àmọ́ tá a bá ka àwọn ẹsẹ Bíbélì kan, ó lè dà bíi pé wọ́n ta kora, ṣùgbọ́n a máa ń lóye irú àwọn ẹsẹ Bíbélì bẹ́ẹ̀ dáadáa tá a bá tẹ̀ lé ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìlànà yìí:
Wo àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e. Bí a kò bá wo ibi tí òǹkọ̀wé kan ti ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ bọ̀, ó lè dà bíi pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ ta kora.
Ronú nípa ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn. Ìdí sì ni pé àwọn tó rí nǹkan lè ṣe àlàyé kedere nípa ohun tí wọ́n rí, ṣùgbọ́n kí ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò tàbí àlàyé tí wọ́n ṣe yàtọ̀ síra.
Ṣe àgbéyẹ̀wò kúlẹ̀kúlẹ̀ ìtàn àti àṣà ìbílẹ̀ tó wé mọ́ ọ̀rọ̀ náà.
Mọ ìyàtọ̀ láàárín àwọn ọ̀rọ̀ tí Bíbélì lò ní tààràtà àti èyí tó lò lọ́nà àpèjúwe.
Fi sọ́kàn pé wọ́n lè sọ pé ẹnì kan ṣe ohun kan kó sì jẹ́ pé òun gan-gan kọ́ ló ṣe nǹkan ọ̀hún. a
Lo ìtumọ̀ Bíbélì tó péye.
Yẹra fún síso ẹ̀kọ́ èké tàbí ẹ̀kọ́ ìsìn tí kì í ṣe òótọ́ pọ̀ mọ́ ohun tí Bíbélì sọ.
Àwọn àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí á jẹ́ ká rí bí àwọn ìlànà méje tá a mẹ́nu kan yìí ṣe fi hàn pé ohun táwọn kan rò pé ó jẹ́ ìtakora nínú Bíbélì kì í ṣe ìtakora rárá.
Ìlànà 1: Ọ̀rọ̀ tí wọ́n sọ ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e
Nígbà tó jẹ́ pé Ọlọ́run sinmi ní ọjọ́ keje, báwo ló ṣe tún wá jẹ́ pé ó ń ṣiṣẹ́ lọ? Àwọn ọ̀rọ̀ tó ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e nínú ìtàn nípa ìṣẹ̀dá tó wà nínú Jẹ́nẹ́sísì jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ náà “ó sì bẹ̀rẹ̀ sí sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ tí ó ti ṣe” ń tọ́ka sí iṣẹ́ ṣíṣẹ̀dá àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ṣe nígbà tó dá ayé. (Jẹ́nẹ́sísì 2:2-4) Ohun tí Jésù sọ kò ta ko èyí nígbà tó sọ pé Ọlọ́run “ń bá a nìṣó ní ṣíṣiṣẹ́ títí di ìsinsìnyí,” ìdí ni pé àwọn iṣẹ́ míì tí Ọlọ́run ń ṣe ni Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. (Jòhánù 5:17) Lára iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe ni bó ṣe mí sí Bíbélì àti bó ṣe ń tọ́ wa sọ́nà tó sì ń bójú tó wa.—Sáàmù 20:6; 105:5; 2 Pétérù 1:21.
Ìlànà 2 àti 3: Ohun tí òǹkọ̀wé ní lọ́kàn àti ohun tí ìtàn sọ
Níbo ni Jésù ti la ojú ọkùnrin afọ́jú náà? Ìwé Lúùkù sọ pé Jésù la ojú ọkùnrin afọ́jú kan “bí ó ti ń sún mọ́ Jẹ́ríkò.” Àkọsílẹ̀ tó jọ èyí, tá a rí nínú ìwé Mátíù sọ nípa àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì kan, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé ìṣẹ̀lẹ̀ náà wáyé bí Jésù “ti ń jáde kúrò ní Jẹ́ríkò.” (Lúùkù 18:35-43; Mátíù 20:29-34) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn òǹkọ̀wé ní lọ́kàn yàtọ̀ síra, síbẹ̀ ìtàn méjèèjì yìí wọnu ara wọn. Ní ti iye àwọn tí ọ̀rọ̀ kàn, Mátíù sọ iye wọn ní pàtó pé àwọn afọ́jú méjì ni, nígbà tí Lúùkù ní tiẹ̀ pe àfíyèsí sí ọkùnrin tí Jésù bá sọ̀rọ̀ gan-gan. Ní ti ibi tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ti wáyé, àwọn awalẹ̀pìtàn rí i pé ìlú méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń jẹ́ Jẹ́ríkò nígbà ayé Jésù. Èyí àtijọ́ tó jẹ́ tàwọn Júù wà ní nǹkan bíi kìlómítà kan àtàbọ̀ sí ìlú Jẹ́ríkò tuntun ti àwọn ará Róòmù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àárín àwọn ìlú méjèèjì yìí ni Jésù wà nígbà tó ṣe iṣẹ́ ìyanu náà.
Ìlànà 4: Àwọn ọ̀rọ̀ àpèjúwe àtèyí tó jẹ́ tààràtà
Ṣé ayé yìí máa pa run? Nínú Oníwàásù 1:4, Bíbélì sọ pé “ilẹ̀ ayé dúró àní fún àkókò tí ó lọ kánrin,” èyí tí àwọn kan gbà pé ó ta ko ọ̀rọ̀ míì tí Bíbélì sọ pé “ayé àti ohun gbogbo tí n bẹ nínú rẹ̀ yóò jóná lúúlúú.” (2 Pétérù 3:10, Bíbélì Mímọ́) Àmọ́ nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà “ayé” máa ń túmọ̀ sí ayé ní tààràtà, ìyẹn pílánẹ́ẹ̀tì wa yìí. Lọ́nà àpèjúwe, ó tún máa ń tọ́ka sí àwọn èèyàn tó ń gbé inú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:1; 11:1) Ọ̀rọ̀ ìparun “ayé” tí 2 Pétérù 3:10 sọ kò túmọ̀ sí pé pílánẹ́ẹ̀tì wa yìí máa jóná, ṣùgbọ́n ó túmọ̀ sí “ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run.”—2 Pétérù 3:7.
Ìlànà 5: Tí wọ́n bá sọ pé ẹnì kan ṣe nǹkan kan
Ta ló wá jíṣẹ́ balógun ọ̀rún fún Jésù ní Kápánáúmù? Ìwé Mátíù 8:5, 6 sọ pé balógun ọ̀rún (ọ̀gá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun) náà fúnra rẹ̀ ló wá sọ́dọ̀ Jésù, nígbà tí ìwé Lúùkù 7:3 sọ pé balógun ọ̀rún náà rán àwọn àgbà ọkùnrin Júù lọ bá Jésù. Ọ̀nà tá a lè gbà lóye ohun tó dà bí ìtakora yìí ni pé ńṣe ni ọ̀gá ẹgbẹ́ ọmọ ogun yẹn sọ ohun tó fẹ́ ṣe, àmọ́ ó rán àwọn àgbà ọkùnrin lọ bá Jésù gẹ́gẹ́ bí aṣojú rẹ̀.
Ìlànà 6: Ìtumọ̀ Bíbélì tó péye
Ṣé gbogbo wa la dẹ́ṣẹ̀? Bíbélì kọ́ wa pé gbogbo wa pátá lá ti jogún ẹ̀ṣẹ̀ látọ̀dọ̀ ọkùnrin àkọ́kọ́, Ádámù. (Róòmù 5:12) Ó jọ pé àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan ta ko ohun tí Bíbélì kọ́ wa yìí, àwọn ìtumọ̀ Bíbélì náà sọ pé ẹni rere “kìí dẹ́ṣẹ̀” tàbí “kò ní máa dẹ́ṣẹ̀.” (1 John 3:6, Bíbélì Mímọ́; Ìròhìn Ayọ̀) Nínú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀, ọ̀rọ̀ ìṣe náà “ẹ̀ṣẹ̀” tó wà nínú 1 Jòhánù 3:6 dún bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́, èyí tó tọ́ka sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láìdáwọ́dúró nínú èdè Gíríìkì. Ìyàtọ̀ wà láàárín ẹ̀ṣẹ̀ tá a jogún, èyí tí a kò lè sá fún àti èyí tí èèyàn mọ̀ọ́mọ̀ dá, tó sì ń tẹ àwọn òfin Ọlọ́run lójú láìdáwọ́dúró. Ìdí nìyẹn tí àwọn ìtumọ̀ Bíbélì kan fi túmọ̀ rẹ̀ lọ́nà tó ṣe rẹ́gí, ọ̀kan lára wọn túmọ̀ ẹsẹ yìí pé, “kì í sọ ẹ̀ṣẹ̀ dídá dàṣà.”—Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
Ìlànà 7: Ohun tí Bíbélì sọ gan-an
Ṣé Jésù bá Ọlọ́run dọ́gba àbí ó kéré sí Ọlọ́run? Jésù sọ nígbà kan pé: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan.” Ó dà bí ẹni pé ohun tó sọ yìí ta ko ọ̀rọ̀ míì tó sọ pé “Baba tóbi jù mí lọ.” (Jòhánù 10:30; 14:28) Tá a bá fẹ́ lóye àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí dáadáa, a ní láti ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa Jèhófà àti Jésù láì fi ẹ̀kọ́ mẹ́talọ́kan tí kò bá Bíbélì mu kún un. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Baba àti Ọlọrun ni Jèhófà jẹ́ sí Jésù. Kódà, Jésù jọ́sìn Ọlọrun. (Mátíù 4:10; Máàkù 15:34; Jòhánù 17:3; 20:17; 2 Kọ́ríńtì 1:3) Jésù kò bá Ọlọ́run dọ́gba.
Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ṣáájú àtèyí tó tẹ̀ lé e nígbà tó ní: “Èmi àti Baba jẹ́ ọ̀kan” fi hàn pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa ìṣọ̀kan tó wà láàárín òun àti Baba rẹ̀, ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run. Jésù sọ nígbà tó yá pé: “Baba wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi, èmi sì wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Baba.” (Jòhánù 10:38) Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ wà ní ìṣọ̀kan bíi ti òun àti Baba rẹ̀, ìdí nìyẹn tó fi gbàdúrà sí Ọlọ́run nípa wọn pé: “Pẹ̀lúpẹ̀lù, mo ti fún wọn ní ògo tí ìwọ ti fi fún mi, kí wọ́n lè jẹ́ ọ̀kan gan-an gẹ́gẹ́ bí àwa ti jẹ́ ọ̀kan. Èmi nínú ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn àti ìwọ nínú ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú mi.”—Jòhánù 17:22, 23.
a Bí àpẹẹrẹ, àpilẹ̀kọ tó sọ̀rọ̀ nípa ibi ìsìnkú tí wọ́n pè ní Taj Mahal nínú ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Encyclopædia Britannica sọ pé “olú ọba Mughal tó ń jẹ́ Shah Jahān ló kọ́ ọ.” Síbẹ̀ òun fúnra rẹ̀ kọ́ ló kọ́ ọ, torí àpilẹ̀kọ náà fi kún un pé “wọ́n gba àwọn òṣìṣẹ́ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún [20,000]” láti kọ́ ibi ìsìnkú náà.