Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ta Ni Ìyàwó Kéènì?

Ta Ni Ìyàwó Kéènì?

Ohun tí Bíbélì sọ

 Kéènì ni ọmọ àkọ́kọ́ tí tọkọtaya àkọ́kọ́ bí. Ọ̀kan lára àwọn àbúrò rẹ̀ obìnrin tàbí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ kan tó jẹ́ obìnrin ló fẹ́. Ohun tí Bíbélì sọ nípa Kéènì àti ìdílé rẹ̀ ló mú ká parí èrò síbẹ̀.

Òtítọ́ nípa Kéènì àti ìdílé rẹ̀

  •   Àtọ̀dọ̀ Ádámù àti Éfà ni gbogbo èèyàn ti ṣẹ̀ wá. Ọlọ́run ‘dá gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn ènìyàn láti ara ọkùnrin kan [Ádámù], láti máa gbé ní ojú gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.’ (Ìṣe 17:26) Éfà, ìyàwó Ádámù, di “ìyá gbogbo ẹni tí ń bẹ láàyè.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:20) Torí náà, ó ní láti jẹ́ pé ọ̀kan lára àwọn ọmọ Ádámù àti Éfà ni Kéènì fẹ́.

  •   Éfà ti kọ́kọ́ bí Kéènì àti Ébẹ́lì àbúrò rẹ̀, kó tó wá bí àwọn ọmọ míì. (Jẹ́nẹ́sísì 4:1, 2) Nígbà tí Kéènì pa àbúrò rẹ̀, Ọlọ́run lé e kúrò, ó wá ń ṣàròyé pé: “Ó . . . dájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rí mi yóò pa mí.” (Jẹ́nẹ́sísì 4:14) Ta ni Kéènì ń bẹ̀rù? Bíbélì sọ pé Ádámù “bí àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin.” (Jẹ́nẹ́sísì 5:4) Ó ṣe kedere pé Kéènì ń wò ó pé àwọn ọmọ míì tí Ádámù àti Éfà bí yìí lè ṣe òun níkà.

  •   Níbẹ̀rẹ̀ ìtàn ẹ̀dá èèyàn, kò ṣàjèjì kéèyàn fẹ́ mọ̀lẹ́bí ẹni. Bí àpẹẹrẹ, àbúrò rẹ̀ obìnrin ni Ábúráhámù, ọkùnrin olódodo náà, fẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 20:12) Òfin Mósè ló kọ́kọ́ ka irú àṣà bẹ́ẹ̀ léèwọ̀, èyí sì jẹ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí Kéènì gbáyé. (Léfítíkù 18:9, 12, 13) Ó jọ pé láyé ìgbà yẹn, àwọn tó bára wọn tan kì í bí ọmọ tó jẹ́ aláàbọ̀ ara bó ṣe máa ń rí lóde òní.

  •   Bí Bíbélì ṣe sọ̀rọ̀ nípa Ádámù, Éfà àti ìdílé wọn fi hàn pé òótọ́ ni ìtàn wọn. Kì í ṣe inú ìwé Jẹ́nẹ́sísì tí Mósè kọ nìkan la ti lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìlà ìdílé Ádámù, ó tún wà nínú ìwé tí àwọn òpìtàn bíi Ẹ́sírà àti Lúùkù kọ. (Jẹ́nẹ́sísì 5:3-5; 1 Kíróníkà 1:1-4; Lúùkù 3:38) Àwọn tó kọ Bíbélì sọ ìtàn Kéènì, ó sì fi hàn pé ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́ ni.​—Hébérù 11:4; 1 Jòhánù 3:12; Júúdà 11.