TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN | JÓÒBÙ
“Mi Ò Ní Fi Ìwà Títọ́ Mi Sílẹ̀!”
Fojú inú wo ọkùnrin kan tó jókòó sílẹ̀, tí eéwo sì bò ó látorí títí dé àtẹ́lẹsẹ̀. Ìbànújẹ́ dorí rẹ̀ kodò, òun nìkan ló dá wà, kódà kò lókun tó fi lè lé àwọn eṣinṣin tó ń kùn ún látorí dé ẹsẹ̀. Bó ṣe jókòó sínú eérú fi hàn pé ìbànújẹ́ tó bá a kọjá kèrémí, kò sóhun míì tó lè ṣe ju pé kó fi àpáàdì máa họ ara tí eéwo ti sọ dìdàkudà. Ẹni táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún dáadáa wá dẹni táwọn èèyàn ń sá fún! Àwọn ọ̀rẹ́, àwọn aládùúgbò àtàwọn mọ̀lẹ́bí rẹ̀ pa á tì. Àwọn èèyàn ń fi ṣe yẹ̀yẹ́, títí kan àwọn ọmọdé. Kódà, ó rò pé Jèhófà Ọlọ́run tí òun ń sìn náà ti kẹ̀yìn sóun, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀.—Jóòbù 2:8; 19:18, 22.
Jóòbù ni ọkùnrin tá à ń sọ yìí. Ọlọ́run sọ nípa rẹ̀ pé: “Kò sí ẹni tó dà bí rẹ̀ ní ayé.” (Jóòbù 1:8) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jèhófà tún dárúkọ Jóòbù nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọkùnrin tó jẹ́ olóòótọ́.—Ìsíkíẹ́lì 14:14, 20.
Bóyá lẹnì kan wà láyé yìí tí kò níṣòro. Ṣé bẹ́ẹ̀ lọ̀rọ̀ tìẹ náà rí àbí ṣe lò ń ti inú ìṣòro kan bọ́ sínú òmíì? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìtàn Jóòbù máa tù ẹ́ nínú gan-an. Ó tún máa jẹ́ kó o túbọ̀ lóye ànímọ́ kan tó yẹ kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ní, ìyẹn ìwà títọ́. Ẹni tó jẹ́ oníwà títọ́ máa ń fi gbogbo ìgbésí ayé ẹ̀ sin Ọlọ́run, kò sì ní yẹsẹ̀ kódà tí nǹkan bá nira gan-an. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká kẹ́kọ̀ọ́ lára Jóòbù.
Ohun Tí Jóòbù Ò Mọ̀
Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀yìn tí Jóòbù kú ni ọkùnrin olóòótọ́ kan tó ń jẹ́ Mósè kọ ìtàn ìgbésí ayé Jóòbù sílẹ̀. Kì í ṣe àwọn ohun tó ṣeé fojú rí tó ṣẹlẹ̀ sí Jóòbù nìkan ni Ọlọ́run mí sí Mósè láti kọ, ó tún ṣàkọsílẹ̀ àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́run.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn yìí, a rí i pé nǹkan ń lọ dáadáa fún Jóòbù, ó sì ń gbádùn ayé ẹ̀. Ọlọ́rọ̀ ni, ìlúmọ̀ọ́ká ni, àwọn èèyàn sì bọ̀wọ̀ fún un nílẹ̀ Úsì tó ṣeé ṣe kó jẹ́ apá ibì kan ní àríwá ilẹ̀ Arébíà. Ó tún jẹ́ ọ̀làwọ́, ó sì máa ń ṣàánú àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́. Ọmọ mẹ́wàá lòun àti ìyàwó rẹ̀ bí. Àmọ́ ohun tó ṣe pàtàkì jù ni pé Jóòbù ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà. Gbogbo ìgbà ló ń gbìyànjú láti múnú Ọlọ́run dùn bíi ti Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù àti Jósẹ́fù tí wọ́n jẹ́ ìbátan rẹ̀. Bíi tàwọn baba ńlá yìí, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jóòbù máa ń rú ẹbọ nítorí àwọn ọmọ rẹ̀.—Jóòbù 1:1-5; 31:16-22.
Àmọ́ ṣàdédé ni nǹkan yí bìrí fún Jóòbù. Ìtàn náà ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́run fún wa, ìyẹn àwọn nǹkan tí Jóòbù fúnra rẹ̀ ò mọ̀. Àwọn áńgẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ pàdé pọ̀ níwájú Jèhófà, Sátánì sì wọlé sáàárín wọn. Jèhófà mọ̀ pé inú Sátánì ò dùn sí Jóòbù, torí náà Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ìwà títọ́ Jóòbù. Sátánì wá dáhùn pé: “Ṣé lásán ni Jóòbù ń bẹ̀rù Ọlọ́run ni? Ṣebí o ti ṣe ọgbà yí i ká láti dáàbò bo òun, ilé rẹ̀ àti gbogbo ohun tó ní?” Sátánì ò tiẹ̀ fẹ́ gbọ́ pé ẹnì kan jẹ́ oníwà títọ́. Ó ṣe tán, ṣe nirú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ túbọ̀ ń jẹ́ kó ṣe kedere pé ọ̀dàlẹ̀ paraku ni Sátánì. Torí náà, Sátánì tẹnu mọ́ ọn pé torí ohun tí Jóòbù ń rí gbà ló fi ń sin Ọlọ́run. Ó sì tún sọ pé tí Jóòbù bá pàdánù gbogbo ohun tó ní, ó máa bú Ọlọ́run níṣojú rẹ̀ gan-an.—Jóòbù 1:6-11.
Bí Jóòbù ò tiẹ̀ mọ̀, Jèhófà fún un láǹfààní láti fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì. Jèhófà gbà kí Sátánì gba gbogbo ohun tí Jóòbù ní. Àmọ́ Jèhófà sọ pé Sátánì ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ kan Jóòbù fúnra rẹ̀. Ni Sátánì bá bẹ̀rẹ̀ sí í mú àjálù lóríṣiríṣi bá Jóòbù. Ní ọjọ́ kan péré, onírúurú ìṣòro bẹ̀rẹ̀ sí í rọ́ lu Jóòbù. Ó gbọ́ pé gbogbo màlúù, kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àgùntàn àtàwọn ràkúnmí òun pátá ló ti kú. Kódà, wọ́n tún pa àwọn ìránṣẹ́ tó ń bójú tó àwọn nǹkan ọ̀sìn rẹ̀ náà. Nígbà tẹ́nì kan ń sọ ohun tójú ẹ̀ rí níbi tí ọ̀kan lára àwọn àjálù náà ti ṣẹlẹ̀, ó sọ pé “ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” ni iná tó jó àwọn ohun ọ̀sìn náà ti wá, èyí tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ààrá. Bí Jóòbù ṣe ń ronú nípa àdánù tóhun tó ṣẹlẹ̀ náà máa fà, ló bá tún gbọ́ pé àjálù tó burú jùyẹn lọ ti ṣẹlẹ̀. Níbi táwọn ọmọ ẹ̀ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá ti ń ṣàjọyọ̀ nílé ẹ̀gbọ́n wọn àgbà, ìjì tó lágbára fẹ́ lu ilé náà lójijì, nilé bá wó pa gbogbo wọn!—Jóòbù 1:12-19.
Kò rọrùn láti mọ bọ́rọ̀ náà ṣe rí lára Jóòbù. Lẹ́yìn tó gbọ́ ohun tó ṣẹlẹ̀, ṣe ló fa aṣọ ara ẹ̀ ya, ó gé irun orí rẹ̀, ó sì gbéra ṣánlẹ̀. Ó wá sọ pé Ọlọ́run tó bù kún òun náà ló gba gbogbo ẹ̀ pa dà. Ṣe ni Sátánì mú kó dà bíi pé Ọlọ́run ló mú àwọn àjálù náà bá Jóòbù. Síbẹ̀, Jóòbù ò bú Ọlọ́run bí Sátánì ṣe sọ pé ó máa ṣe. Kàkà bẹ́ẹ̀, ohun tí Jóòbù sọ ni pé: “Ká máa yin orúkọ Jèhófà títí lọ.”—Jóòbù 1:20-22.
“Ó Dájú Pé Ó Máa Bú Ọ”
Ṣe ni inú túbọ̀ ń bí Sátánì, tó sì ń wá bí nǹkan ṣe máa túbọ̀ nira fún Jóòbù. Sátánì tún wá nígbà míì táwọn áńgẹ́lì ń wọlé wá síwájú Jèhófà. Ni Jèhófà bá tún sọ̀rọ̀ nípa bí Jóòbù ṣe pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ lójú ọ̀pọ̀ àtakò. Sátánì wá sọ pé: “Awọ dípò awọ. Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀. Àmọ́, kí nǹkan lè yí pa dà, na ọwọ́ rẹ, kí o sì kọ lu egungun àti ara rẹ̀, ó dájú pé ó máa bú ọ níṣojú rẹ gan-an.” Sátánì gbà pé tí àìsàn bá kọ lu Jóòbù, ó máa bú Ọlọ́run. Torí pé Jèhófà fọkàn tán Jóòbù, ó gbà kí Sátánì ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Àmọ́ Jèhófà sọ pé Sátánì ò gbọ́dọ̀ pa Jóòbù.—Jóòbù 2:1-6.
Kò pẹ́ sígbà yẹn ni nǹkan nira fún Jóòbù bá a ṣe sọ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Ẹ wo bó ṣe máa rí lára ìyàwó rẹ̀ nírú àkókò bẹ́ẹ̀. Àdánù tàwọn ọmọ mẹ́wẹ̀ẹ̀wá tó kú ò tíì kúrò nílẹ̀, ó tún di pé kó máa tọ́jú ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ̀rora. Ló bá fìkanra sọ fún Jóòbù pé: “Ṣé pé o ò tíì fi ìwà títọ́ rẹ sílẹ̀? Sọ̀rọ̀ òdì sí Ọlọ́run, kí o sì kú!” Jóòbù ò rò pé ìyàwó òun lè sọ irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ láé! Torí náà Jóòbù sọ pé ó ń sọ̀rọ̀ bí aláìnírònú. Síbẹ̀, Jóòbù ò bú Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ sì ni kó fi ẹnu rẹ̀ dẹ́ṣẹ̀.—Jóòbù 2:7-10.
Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ọ̀rọ̀ yìí kan ìwọ náà? Kíyè sí i pé kì í ṣe Jóòbù nìkan ni Sátánì fẹ̀sùn burúkú náà kàn. Gbogbo èèyàn ló ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé: “Gbogbo ohun tí èèyàn bá ní ló máa fi dípò ẹ̀mí rẹ̀.” Ohun tí Sátánì ń sọ ni pé kò sẹ́ni tó lè jẹ́ adúróṣinṣin sí Ọlọ́run délẹ̀délẹ̀. Kódà, ó ní ìwọ gan-an ò nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run tọkàntọkàn àti pé kíákíá ni wàá fi Ọlọ́run sílẹ̀ tó o bá kojú ìṣòro tó le ju ẹ̀mí ẹ lọ. Ohun tí Sátánì ń dọ́gbọ́n sọ ni pé onímọtara-ẹni-nìkan bíi tòun nìwọ náà. Ṣé wàá ṣe ohun táá fi hàn pé òpùrọ́ ni Sátánì? Torí gbogbo wa pátá la láǹfààní láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 27:11) Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ohun míì tí Sátánì ṣe fún Jóòbù.
Àwọn Olùtùnú Èké
Ọ̀rẹ́ tàbí ojúlùmọ̀ ni Bíbélì pe àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó mọ Jóòbù bí ẹni mowó yìí. Nígbà tí wọ́n gbọ́ àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i, wọ́n rìnrìn àjò wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti tù ú nínú. Wọn ò tiẹ̀ dá a mọ̀ nígbà tí wọ́n rí i lókèèrè. Gbogbo ara ń rò ó, ara rẹ̀ sì dúdú látòkè délẹ̀ látàrí àìsàn tó ti ba àwọ̀ ara rẹ̀ jẹ́, kò tiẹ̀ jọ pé òun ni Jóòbù tí wọ́n mọ̀ tẹ́lẹ̀. Àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí, ìyẹn Élífásì, Bílídádì àti Sófárì ṣe bí ẹni pé inú àwọn bà jẹ́ bí Jóòbù ṣe ń jìyà, wọ́n ń sunkún kíkankíkan, wọ́n sì ń da iyẹ̀pẹ̀ sórí ara wọn. Ni wọ́n bá jókòó sílẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jóòbù, wọn ò sì sọ nǹkan kan. Odindi ọ̀sẹ̀ kan ni wọ́n fi wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, tọ̀sán-tòru, tí wọn ò sì bá a sọ̀rọ̀. Àṣìṣe ló máa jẹ́ tá a bá rò pé torí kí wọ́n lè tù ú nínú ni wọ́n ṣe dákẹ́ tí wọn ò sọ nǹkan kan. Ohun tó jẹ́ ká mọ̀ bẹ́ẹ̀ ni pé wọn ò gbìyànjú láti mọ bí ìṣòro tó bá Jóòbù ṣe le tó, wọ́n kàn rí i pé inú ìrora tó lé kenkà ló wà ni.—Jóòbù 2:11-13; 30:30.
Nígbà tó yá, Jóòbù fúnra ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀. Ó sọ bí ìyà tó ń jẹ òun ṣe pọ̀ tó nígbà tó fi ọjọ́ tí wọ́n bí i gégùn-ún. Ó wá sọ ohun kan tó gbà pé òun ló jẹ́ kí òun máa jìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀. Ó rò pé Ọlọ́run ló fa gbogbo ìṣòro tó dé bá òun! (Jóòbù 3:1, 2, 23) Síbẹ̀, Jóòbù ṣì nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, ó kàn nílò ìtùnú lójú méjèèjì ni. Àmọ́ nígbà táwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹ́ta yìí bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀, ó rí i pé kò bá ti dáa ká ní wọn ò sọ̀rọ̀ rárá torí kò sí ọ̀rọ̀ ìtùnú kankan lẹ́nu wọn.—Jóòbù 13:5.
Élífásì tó dàgbà ju Jóòbù lọ ló kọ́kọ́ sọ̀rọ̀, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé òun ló dàgbà jù láàárín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta náà. Nígbà tó yá, àwọn méjì tó kù náà sọ tẹnu wọn. A lè sọ pé ńṣe làwọn méjì tó kù yìí fi àìgbọ́n ronú bíi ti Élífásì. Ó lè fẹ́ jọ pé kò sóhun tó burú nínú ohun táwọn ọkùnrin yẹn sọ torí ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ nípa Ọlọ́run tó sì dà bí òótọ́ làwọn náà sọ. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ pé Ọlọ́run tóbi lọ́ba, pé ó máa ń fìyà jẹ àwọn ẹni burúkú, ó sì máa ń san àwọn tó bá ṣe rere lẹ́san. Bó ti wù kó rí, àtìbẹ̀rẹ̀ ló ti hàn pé ọ̀rọ̀ Jóòbù ò jẹ wọ́n lógún. Bí àpẹẹrẹ, Élífásì sọ àwọn ọ̀rọ̀ tó dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu àmọ́ tí ìparí èrò ẹ̀ kù díẹ̀ káàtó. Ó sọ pé níwọ̀n bí Ọlọ́run ti jẹ́ ẹni rere, tó sì máa ń fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú, kí ni ìyà tó ń jẹ Jóòbù fi hàn nígbà náà? Ṣé kì í ṣe pé Jóòbù ti ṣe nǹkan tí kò dáa nìyẹn?—Jóòbù 4:1, 7, 8; 5:3-6.
Kò yani lẹ́nu pé Jóòbù ò gbà pé òótọ́ ni Élífásì sọ. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló kọ̀ ọ́. (Jóòbù 6:25) Ṣùgbọ́n, ó dá àwọn agbaninímọ̀ràn mẹ́ta yìí lójú pé Jóòbù ti dẹ́ṣẹ̀ tí kò fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ẹ̀, torí náà wọ́n gbà pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ ló ń jẹ. Élífásì fi ẹ̀sùn kan Jóòbù pé kò mọ̀wọ̀n ara rẹ̀, ó ní ìkà ni àti pé kò ní ìbẹ̀rù Ọlọ́run rárá àti rárá. (Jóòbù 15:4, 7-9, 20-24; 22:6-11) Sófárì sọ fún Jóòbù pé kó má ṣe lọ́wọ́ sí àwọn nǹkan burúkú mọ́, kó má sì máa mu ẹ̀ṣẹ̀ bí ẹni mumi. (Jóòbù 11:2, 3, 14; 20:5, 12, 13) Ọ̀rọ̀ tí Bílídádì sọ ló wá burú jù. Ó sọ pé ó dájú pé àwọn ọmọ Jóòbù ti ṣẹ̀, torí náà ohun tó tọ́ sí wọn ló ṣẹlẹ̀ sí wọn yẹn!—Jóòbù 8:4, 13.
Wọ́n Bẹnu Àtẹ́ Lu Ìwà Títọ́ Rẹ̀!
Àwọn èèyànkéèyàn yẹn tún ṣe ohun tó burú jáì. Yàtọ̀ sí pé wọ́n ní Jóòbù kì í ṣe olóòótọ́ tàbí pé ojú ayé ló ń ṣe, wọ́n tún sọ pé kò sí èrè kankan nínú kéèyàn máa sapá láti jẹ́ oníwà títọ́! Níbẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ Élífásì, ó sọ pé òun rí ẹ̀mí àìrí kan nínú ìran, ó sì kó jìnnìjìnnì bá òun. Ibi tó parí ọ̀rọ̀ sí lẹ́yìn tó bá ẹ̀mí èṣù náà pàdé kò dáa rárá, ó sọ pé Ọlọ́run “kò ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ó sì ń wá àṣìṣe àwọn áńgẹ́lì rẹ̀.” Ohun tó ń dọ́gbọ́n sọ ni pé, bó ti wù káwa èèyàn gbìyànjú tó, a ò lè tẹ́ Ọlọ́run lọ́rùn. Nígbà tó yá, Bílídádì sọ pé ìwà títọ́ Jóòbù kò já mọ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run, torí pé kò yàtọ̀ sí ìdin lásánlàsàn!—Jóòbù 4:12-18; 15:15; 22:2, 3; 25:4-6.
Ǹjẹ́ o ti wọ́nà láti tu ẹnì kan tó wà nínú ìrora tó le gan-an nínú rí? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé kò rọrùn. Ọ̀pọ̀ nǹkan la lè kọ́ látinú ohun táwọn ọ̀rẹ́ Jóòbù tí kò ronú jinlẹ̀ yẹn ṣe, àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé ká mọ àwọn nǹkan tí kò yẹ kéèyàn sọ. Ọ̀pọ̀ lára ọ̀rọ̀ táwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn sọ ló dà bíi pé ó bọ́gbọ́n mu, àmọ́ ó ṣe kedere pé wọn ò káàánú Jóòbù rárá, kódà wọn ò dárúkọ rẹ̀ rárá nínú ọ̀rọ̀ wọn! Wọn ò wo ti ẹ̀dùn ọkàn Jóòbù rárá, wọn ò sì rídìí tó fi yẹ káwọn fi ahọ́n tútù bá a sọ̀rọ̀. * Torí náà, tí ẹnì kan tó sún mọ́ ẹ bá níṣòro, fi àánú hàn sí i, jẹ́ kó mọ̀ pé o nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ tọkàntọkàn àti pé ọ̀rọ̀ ẹ̀ jẹ ẹ́ lógún. Sọ àwọn ohun tó máa jẹ́ kí ìgbàgbọ́ ẹni náà túbọ̀ lágbára, kó o sì fún un níṣìírí. Jẹ́ kó rídìí tó fi yẹ kó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run, kó sì gbà pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, ó ń fi inú rere hàn sí wa àti pé onídàájọ́ òdodo ni. Ohun tí Jóòbù ì bá ṣe gẹ́lẹ́ nìyẹn ká sọ pé àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ló wà nípò tí òun wà. (Jóòbù 16:4, 5) Ó dáa, kí ni Jóòbù wá ṣe bí wọ́n ṣe ń pẹ̀gàn ìwà títọ́ rẹ̀ ṣáá?
Jóòbù Jẹ́ Olóòótọ́
Ẹ rántí pé nǹkan ò dẹrùn rárá fún Jóòbù tẹ́lẹ̀, ẹ̀yìn ìyẹn làwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tún bẹ̀rẹ̀ sí í sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí i. Níbẹ̀rẹ̀, Jóòbù gbà pé òun ń sọ àwọn “ọ̀rọ̀ ẹhànnà” àti pé “ọ̀rọ̀ tí ẹni tí ìdààmú bá” ló ń jáde lẹ́nu òun nígbà míì. (Jóòbù 6:3, 26) Ó dájú pé a mọ ìdí tó fi sọ bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé nǹkan nira fún un gan-an nígbà yẹn, ó sì hàn nínú ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé kò mọ ohun tó fa ìṣòro náà. Láìròtẹ́lẹ̀ làwọn àjálù yẹn ń dé bá a, tí ọ̀kan ń rọ́ lu òmíì, ó sì jọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn kọjá agbára èèyàn, torí ẹ̀ Jóòbù gbà pé Jèhófà ló wà nídìí ẹ̀. Àmọ́ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì kan ti wáyé tí Jóòbù ò mọ̀, ìdí nìyẹn tí èrò ẹ̀ kò fi tọ̀nà.
Síbẹ̀, Jóòbù ní ìgbàgbọ́ tó lágbára gan-an. A rí bí ìgbàgbọ́ tó ní ṣe lágbára tó nínú èsì tó ń fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀. Òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tí Jóòbù sọ, wọ́n ń tuni lára, wọ́n sì ń fúnni níṣìírí. Nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun àgbàyanu tí Ọlọ́run dá, ó yin Ọlọ́run lógo, ó sì sọ àwọn nǹkan tó jẹ́ pé kò sí èèyàn kankan tó lè mọ̀ ọ́n láìsí ìrànwọ́ Ọlọ́run. Bí àpẹẹrẹ, ó sọ pé Jèhófà “fi ayé rọ̀ sórí òfo.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn náà làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó mọ̀ pé bó ṣe rí gan-an nìyẹn. * (Jóòbù 26:7) Jóòbù tún sọ̀rọ̀ nípa ìrètí tó ní lọ́jọ́ iwájú, ìrètí yìí kan náà làwọn ọkùnrin olóòótọ́ míì náà ní. Jóòbù gbà pé tí òun bá tiẹ̀ kú, Ọlọ́run máa rántí òun, pé ó máa wu Ọlọ́run gan-an láti rí òun, ó sì máa jí òun dìde.—Jóòbù 14:13-15; Hébérù 11:17-19, 35.
Ọ̀rọ̀ nípa ìwà títọ́ ńkọ́? Élífásì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ méjì gbà pé ìwà títọ́ èèyàn ò jẹ́ nǹkan kan lójú Ọlọ́run. Ṣé Jóòbù gbà pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yìí? Ká má rí i! Jóòbù gbà pé Ọlọ́run mọyì ìwà títọ́ wa. Ó fìgboyà sọ nípa Jèhófà pé: “Ó máa wá mọ ìwà títọ́ mi.” (Jóòbù 31:6) Ó wá ṣe kedere sí Jóòbù pé ńṣe làwọn tó pe ara wọn ní ọ̀rẹ́ rẹ̀ yìí ń sọ òkò ọ̀rọ̀ sí òun láti bẹnu àtẹ́ lu ìwà títọ́ òun. Ìyẹn ló mú kí Jóòbù sọ ọ̀rọ̀ tó pọ̀ gan-an, ọ̀rọ̀ gígùn tó fi fún wọn lésì kẹ́yìn yẹn ló jẹ́ kí ẹnu àwọn ọkùnrin mẹ́ta yẹn wọhò.
Jóòbù mọ̀ pé ojoojúmọ́ ló yẹ kóun máa pa ìwà títọ́ mọ́. Torí náà, ó ṣàlàyé bóun ṣe ń pa ìwà títọ́ mọ́ nínú gbogbo ohun tóun ń ṣe. Bí àpẹẹrẹ, Jóòbù jẹ́ kó ṣe kedere pé òun kì í bọ̀rìṣà, òun máa ń fi inú rere hàn sáwọn míì, òun sì máa ń bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn, òun kì í ṣe ìṣekúṣe, òun mọyì ìyàwó òun, òun sì nífẹ̀ẹ́ ẹ̀ gan-an. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jóòbù fi hàn pé tọkàntara lòun fi ń sin Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́. Èyí ló mú kó lè sọ pé: “Títí màá fi kú, mi ò ní fi ìwà títọ́ mi sílẹ̀!”—Jóòbù 27:5; 31:1, 2, 9-11, 16-18, 26-28.
Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Jóòbù
Bíi ti Jóòbù, ṣé ìwọ náà gbà pé ó yẹ kéèyàn pa ìwà títọ́ mọ́? Ó lè rọrùn láti sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ Jóòbù gbà pé ìwà títọ́ kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹnu lásán. Tá a bá ń ṣègbọràn sí Jèhófà, tá a sì ń ṣe ohun tó tọ́ lójú rẹ̀ lójoojúmọ́ kódà bá a tiẹ̀ ń kojú ìṣòro, ṣe là ń fi hàn pé a jẹ́ oníwà títọ́ àti pé tọkàntọkàn la fi ń sin Jèhófà. Bíi ti Jóòbù, táwa náà bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé inú Jèhófà á dùn sí wa, a sì máa mú kí ìbànújẹ́ bá Sátánì tó jẹ́ ọ̀tá Ọlọ́run. Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tó dáa jù nìyẹn tá a lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Jóòbù, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Àmọ́ ìtàn náà ò tíì parí o. Jóòbù ti gbàgbé ohun tó ṣe pàtàkì jù, bó ṣe máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé olóòótọ́ lòun ló gbájú mọ́ dípò kó dá orúkọ Ọlọ́run láre. Torí náà, ó nílò ẹni tó máa tún èrò ẹ̀ ṣe kí èrò ẹ̀ lè bá ti Ọlọ́run mu. Bákan náà, torí pé inú ìrora ló ṣì wà, ó nílò ìtùnú lójú méjèèjì. Kí ni Jèhófà máa wá ṣe fún ọkùnrin tó nígbàgbọ́ tó sì ń pa ìwà títọ́ mọ́ yìí? A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àpilẹ̀kọ míì lára ọ̀wọ́ yìí.
^ ìpínrọ̀ 17 Ó yani lẹ́nu pé Élífásì rò pé ohùn pẹ̀lẹ́ lòun àtàwọn ọ̀rẹ́ òun fi bá Jóòbù sọ̀rọ̀ torí pé wọn ò jágbe mọ́ ọn. (Jóòbù 15:11) Àmọ́ òótọ́ ibẹ̀ ni pé téèyàn ò bá ṣọ́ra, ọ̀rọ̀ téèyàn fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ sọ gan-an lè dunni wọnú eegun.
^ ìpínrọ̀ 19 Ìwádìí tí wọ́n ṣe fi hàn pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] ọdún lẹ́yìn ìgbà tí Jóòbù sọ̀rọ̀ yẹn làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì tó rí i pé kò sídìí tó fi yẹ kí ayé jókòó sórí ohunkóhun. Ìgbà táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ya àwọn fọ́tò kan látinú òfúrufú làwọn èèyàn tó rí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé òótọ́ pọ́ńbélé ni Jóòbù sọ.