Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?

Báwo Ni Mo Ṣe Lè Gbọ́kàn Kúrò Lórí Ìbálòpọ̀?

 “Èrò nípa ìbálòpọ̀ á ṣàdédé gbà mí lọ́kàn. Ńṣe ló dà bíi pé ẹlòmíì ló ń darí ìrònú mi.”​—Vera.

 “Ó jọ pé kò ṣeé ṣe fún mi láti kápá èrò mi lórí ìbálòpọ̀, ó wà lára ohun tó ṣòro jù lọ fún mi.”​—John.

 Ṣé ohun tó ń ṣẹlẹ sí ẹ jọ ti Vera tàbí John? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, àpilẹ̀kọ yìí á ràn ẹ́ lọ́wọ́.

 Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì?

  Ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Alex sọ pé, “Mọ̀lẹ́bí mi kan sọ fún mi pé tí Ọlọ́run ò bá fẹ́ kí n ní ìbálòpọ̀ kò ní dá mi lọ́nà tá á fi máa wù mí láti ní ìbálòpọ̀.”

 Apá kan ohun tí mọ̀lẹ́bí Alex sọ jóòótọ́, Ọlọ́run dá wa lọ́nà tá a fi lè fẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ lóòótọ́, ó sì nídìí tó fi dá wa bẹ́ẹ̀. Ìpasẹ̀ ìbálòpọ̀ ni wọ́n fi bí àwọn èèyàn tó wà láyé lónìí. Torí náà, kí nìdí tí wàá fi máa da ara rẹ láàmú pé o fẹ́ gbọ́kàn kúrò lórí ìbálòpọ̀? Ìdí méjì tó ṣe pàtàkì rèé:

  •   Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run fẹ́ kí ìbálòpọ̀ mọ sáàárín ọkùnrin àti obìnrin tí wọ́n ti fẹ́ra wọn sílé.​—Jẹ́nẹ́sísì 1:28; 2:24.

     Tó o bá bọ̀wọ̀ fún ìlànà Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ yìí, tó o sì jẹ́ àpọ́n, tó o wá lọ ń ronú nípa ìbálòpọ̀ nígbà gbogbo, ìnú ẹ á kàn máa bà jẹ́ ni. Kódà ó lè mú kó o fẹ́ ìbálòpọ̀ tí kò yẹ, ìyẹn sì ti mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ kábàámọ̀ nígbà tó yá.

  •   Gbígbé ọkàn kúrò lórí ìbálòpọ̀ lè mú kó o kọ́ ìkóra-ẹni-níjàánu tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà míì nígbèésí ayé rẹ.​—1 Kọ́ríńtì 9:25.

 Ìkóra-ẹni-níjàánu ṣe pàtàkì torí á jẹ́ kó o ṣàṣeyọrí nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú. Òótọ́ ni, torí ìwádìí kan fi hàn pé tí àwọn ọmọ tó ní ìkóra-ẹni-níjàánu bá dàgbà, wọn kì í sábà ní ìṣòro àìlera, wọn kì í sábà ṣàníyàn torí àìlówó lọ́wọ́, wọn kì í sì í sábà rú òfin. a

   Kí nìdí tó fi ṣòro?

 Yàtọ̀ sí pé à ń gbé láyé tí ìbálòpọ̀ ti gba àwọn èèyàn lọ́kàn, àwọn kẹ́míkà kan nínú ara tún máa ń mú kó nira láti gbé ọkàn kúrò lórí ìbálòpọ̀.

  “Ó dà bíi pé ọ̀pọ̀ eré orí tẹlifísọ̀n ló ń fi hàn pé ó dáa láti máa ní ìbálòpọ̀ láì ṣègbéyàwó, tí wọ́n ò sì ní fi hàn pé ewu wà ńbẹ̀. Ó rọrùn láti máa ro èrò tí kò tọ́ nígbà tí wọn ò bá fi hàn pé ìbálòpọ̀ tí kò yẹ máa ń pani lára.”​—Ruth.

 “Níbi iṣẹ́, mo máa ń gbọ́ ọ̀pọ̀ ìsọkúsọ nípa ìbálòpọ̀, ojúmìító sì máa ń mú kí n fẹ́ mọ púpọ̀ sí i. Wọ́n mú kí ìṣekúṣe dà bí ohun tó dáa débi tó fi nira láti gbà pé ó burú.”​—Nicole.

 “Ó rọrùn kéèyàn gbàgbéra nígbà tó bá ń wo fọ́tò lórí ìkànnì àjọlò. Gbàrà tó o bá ti rí àwòrán ìṣekúṣe kan, á ṣòro gan-an fún ẹ láti gbé e kúrò lọ́kàn!”​—Maria.

 Àwọn nǹkan tá a ti mẹ́nu bà yìí lè mú kó máa ṣe ẹ́ bíi ti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Ó ní: “Nígbà tí mo bá fẹ́ ṣe ohun tí ó tọ́, ohun tó burú ló máa ń wà lọ́kàn mi.”​—Róòmù 7:21.

Má ṣe jẹ́ kí èrò tí kò tọ́ gbà ẹ́ lọ́kàn

 Ohun tó o lè ṣe

 Darí ìrònú rẹ sí nǹkan míì. Sapá láti máa ro àwọn nǹkan míì tí ò jẹ́ mọ́ ìbálòpọ̀. Àwọn nǹkan míì náà lè jẹ́ eré tó o fẹ́ràn, eré ìdárayá, eré ìmárale tàbí àwọn nǹkan míì tó o fẹ́ràn láti máa ṣe. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Valerie sọ pé: “Kíka Bíbélì á ràn ẹ́ lọ́wọ́, torí èrò Ọlọ́run ló wà nínú ẹ̀, tí èrò Ọlọ́run bá sì wà lọ́kàn ẹ, ọkàn ẹ ò ní tètè máa lọ sí ohun tí kò tọ́.”

 Lóòótọ́, èrò nípa ìbálòpọ̀ lè wá sí ẹ lọ́kàn, àmọ́ ohun tó o máa ṣe sí èrò náà kù sọ́wọ́ rẹ. O ní agbára láti mú èrò náà kúrò lọ́kàn rẹ tó o ba fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

 “Ti mo bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú nípa ìbálòpọ̀, màá mọ̀ọ́mọ̀ darí èrò mi sí nǹkan míì. Mo tún ń sapá gan-an láti mọ ohun tó ń jẹ́ kí n máa ronú lórí ìbálòpọ̀, bóyá orin ni tàbí àwòrán kan kí n lè pa á rẹ́ kúrò níbi tó wà.”​—Helena.

 Ìlànà Bíbélì: “Ohunkóhun tó jẹ́ òdodo, ohunkóhun tó jẹ́ mímọ́, [tàbí,“tó mọ́” àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé], . . . ẹ máa ronú lórí àwọn nǹkan yìí.”​—Fílípì 4:8

  Yan ọ̀rẹ́ rere. Tó bá jẹ́ pé ìgbà gbogbo làwọn ọ̀rẹ́ rẹ ń sọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀, ó máa ṣòro fún ẹ láti gbọ́kàn kúrò lórí ìbálòpọ̀.

 “Nígbà tí mo wà lọ́dọ̀ọ́, ó máa ń ṣòro fún mi láti máa ro ohun tó tọ́, àwọn ọ̀rẹ́ mi ló mú kó ṣòro gan-an. Tó o bá wà láàárín àwọn tó ń gbé ìṣekúṣe lárugẹ, èròkérò ni wàá máa rò, ìyẹn á mú kí ìfẹ́ ìṣekúṣe máa lágbára sí i lọ́kàn ẹ.”​—Sarah.

 Ìlànà Bíbélì: “Ẹni tó ń bá ọlọ́gbọ́n rìn yóò gbọ́n, àmọ́ ẹni tó ń bá òmùgọ̀ da nǹkan pọ̀ yóò rí láburú.”​—Òwe 13:20.

 Sá fún eré ìnàjú tí kò tọ́. Kì í ṣe nǹkan àṣírí mọ́ pé gbogbo àwọn eré ìnàjú ló ń gbé ìbálòpọ̀ lárugẹ. Nicole sọ pé: “Ní tèmi, orin ló nípa lórí mi jù lọ. Ó máa ń mú kí ìfẹ́ ìbálòpọ̀ lágbára lọ́kàn mi débi pé mi ò ní lè ro nǹkan míì mọ́.”

 “Mo bẹ̀rẹ̀ sí í wo fíìmù àti eré orí tẹlifísọ̀n tó ń fi ọ̀pọ̀ ìbálòpọ̀ hàn. Kí n tó mọ̀, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ronú gan-an nípa ìbálòpọ̀. Ó rọrùn fún mi láti mọ ìdí tí èrò yẹn fi ń wá sí mi lọ́kàn. Gbàrà tí mi ò wo fíìmù àti eré orí tẹlifísọ̀n tó ní ìbálòpọ̀ mọ́ ni mi ò fi bẹ́ẹ̀ ronú nípa ìbálòpọ̀ mọ́. Nígbà tí mò ń yan eré ìnàjú tó dáa láti wó, ó túbọ̀ rọrùn fún mi láti gbọ́kàn kúrò lórí èrò tí kò tọ́.”​—Joanne.

 Ìlànà Bíbélì: “Kí a má tilẹ̀ mẹ́nu kan ìṣekúṣe àti ìwà àìmọ́ èyíkéyìí tàbí ojúkòkòrò láàárín yín.”​—Éfésù 5:3.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Àwọn kan rò pé ìfẹ́ ìbálòpọ̀ ṣè pàtàkì fún àwọn gan-an, torí náà, àwọn ò lè pa á mọ́ra tàbí kò yẹ káwọn kápá rẹ̀. Àmọ́ Bíbélì sọ ohun tó yàtọ̀ sí èrò wọn. Ọlọ́run buyì kún wa nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tórí ó jẹ́ ká mọ̀ pé a kápá èrò wa.

  Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa di tuntun nínú agbára tó ń darí ìrònú yín.”​—Éfésù 4:23.

a Ìdí míì tó o fi ní láti ní ìkóra-ẹni-níjàánu nísinsìnyí tó ò tíì ṣègbéyàwó ni pé o máa nílò rẹ̀ nígbà tó ó bá ṣègbéyàwó.