ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Kí Ló Dé Táwọn Òbí Mi Ò Fẹ́ Kí N Gbádùn Ara Mi?
Àwọn ọ̀rẹ́ ẹ ní kẹ́ ẹ jọ jáde lópin ọ̀sẹ̀. O béèrè lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ bóyá o lè lọ, àmọ́ wọn ò rò ó lẹ́ẹ̀mejì kí wọ́n tó sọ pé, “Rárá.” Ìdáhùn wọn ò yà ẹ́ lẹ́nu, torí ohun tí wọ́n máa ń sọ nìyẹn.
Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a máa dáhùn àwọn ìbéèrè yìí
Kí nìdí táwọn òbí mi kì í fẹ́ kí n ṣe ohun tó wù mí?
Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà làwọn òbí ẹ kì í jẹ́ kó o ṣe ohun tó wù ẹ́, ó lè máa ṣe ẹ́ bíi pé wọn ò fẹ́ kó o gbádùn ara ẹ.
Bó ṣe rí lára ọ̀dọ́bìnrin kan tó ń jẹ́ Marie nìyẹn nígbà tó kọ́kọ́ ra fóònù. Ó sọ pé: “Oríṣiríṣi òfin ni dádì mi ṣe. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n sọ àwọn nǹkan tí mo lè gbà sórí ẹ̀, àwọn tí mo lè bá sọ̀rọ̀ àti ìgbà tí mo lè bá wọn sọ̀rọ̀ dà. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, àwọn ọ̀rẹ́ mi lè ṣe ohun tó bá wù wọ́n.”
Ohun tó yẹ kó o ronú lé: Ṣé dádì Marie ò fẹ́ kó gbádùn ara ẹ̀ lóòótọ́? Kí làwọn ohun tó ṣeé ṣe kó máa rò?
Gbìyànjú èyí wò: Ká sọ pé òbí ni ẹ́, ọmọ ẹ sì ṣẹ̀ṣẹ̀ ra fóònù. Kí làwọn nǹkan tó ṣeé ṣe kó o máa rò? Àwọn òfin wo lo máa ṣe kó o lè dáàbò bo ọmọ ẹ? Kí lo máa ṣe tí ọmọ ẹ bá sọ pé o ò fẹ́ kóun gbádùn ara òun?
“Dádì mi máa ń sọ pé, ‘Ìwọ náà máa di òbí lọ́jọ́ kan.’ Ìyẹn máa ń jẹ́ kí n rí i pé òótọ́ ọ̀rọ̀ ni wọ́n ń bá mi sọ, ó sì máa ń jẹ́ kí n rídìí tí wọ́n fi ní kí n máa ṣe àwọn nǹkan kan. Ká lémi náà ti bímọ ni, ohun tí dádì mi fẹ́ kí n ṣe lèmi náà á fẹ́ káwọn ọmọ mi máa ṣe.”—Tanya.
Kí ni mo lè ṣe káwọn òbí mi lè gbà kí n ṣe ohun tó wù mí?
“Tó o bá tiẹ̀ kígbe látòní dọ̀la, ìyẹn ò ní kí ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yanjú, ṣe ni wàá tiẹ̀ tún kó àárẹ̀ bá ara ẹ àtàwọn òbí ẹ. Tó o bá ń bá àwọn òbí ẹ jiyàn, wọ́n á gbà pé o ò tíì gbọ́n, àti pé àwọn ṣì gbọ́dọ̀ máa mójú tó ẹ.”—Richard.
“Tèmi làwọn òbí mi ń rò tí wọ́n bá ní kí n má ṣe nǹkan kan. Kì í ṣe pé àwọn òbí mi ò fẹ́ kí n gbádùn ara mi; wọn ò kàn fẹ́ kí n ṣe ohun táá kó mi síṣòro ni.”—Ivy
Ìlànà Bíbélì: “Gbogbo bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára òmùgọ̀ ló máa ń sọ jáde, àmọ́ ọlọ́gbọ́n máa ń mú sùúrù.”—Òwe 29:11.
“Mo máa ń dọ́gbọ́n ṣe àwọn nǹkan tí dádì mi ní kí n má ṣe lórí fóònù mi. Bí àpẹẹrẹ, mo lè máa fọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sáwọn ọ̀rẹ́ mi lálẹ́ àbí kí n máa dé àwọn ibi tí wọ́n ní kí n má dé lórí fóònù. Tí dádì mi bá wá mọ̀, ṣe ni wọ́n á fún mi lófin tó ju ti tẹ́lẹ̀ lọ torí mi ò ṣe ohun táá jẹ́ kí wọ́n fọkàn tán mi. Kò dáa rárá kéèyàn máa ṣe ohun tí wọ́n bá ní kó má ṣe.”—Marie.
“Ṣe sùúrù. Ó lè ṣe díẹ̀ káwọn òbí ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í gbà ẹ́ láyè láti ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ní kó o má ṣe tẹ́lẹ̀, àmọ́ tí wọ́n bá rí i pé ò ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ní kó o ṣe, wọ́n lè gbà ẹ́ láyè láti ṣe ohun tó o bá fẹ́.”—Melinda.
Ìlànà Bíbélì: “Ẹ máa gbọ́ràn sí àwọn òbí yín lẹ́nu nínú ohun gbogbo.”—Kólósè 3:20.
“Má rò pé tó o bá ń tẹnu mọ́rọ̀ ìyẹn á jẹ́ kó o rí nǹkan tó ò ń fẹ́.”—Natalie.
“Àwọn òbí máa ń fẹ́ rí i pé ọmọ àwọn mọ nǹkan tó ń ṣe. Torí náà, tí mo bá ń bá àwọn òbí mi sọ̀rọ̀, mo máa ń jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé mo ti ro ọ̀rọ̀ náà dáadáa, dípò kí n máa sọ bó ṣe rí lára mi. Tí mo bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀rọ̀ mi máa ń tà létí wọn.”—Joseph.
Ìlànà Bíbélì: “Bọlá fún bàbá rẹ àti ìyá rẹ.”—Éfésù 6:2.