Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ

Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Ń Kúrò Nílé?

Ṣé Mo Ti Tó Ẹni Tó Ń Kúrò Nílé?

 Téèyàn bá fẹ́ kó kúrò nílé, ó máa ń dùn mọ́ọ̀yàn, ó sì tún máa ń dáyà jáni. Báwo lo ṣe máa mọ̀ bóyá o ti tó ẹni tó ń dá gbé láyè ara ẹ̀?

 Ṣàyẹ̀wò ìdí tó o fi fẹ́ ṣe é

 Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó o fi lè pinnu pé o fẹ́ kúrò nílé, àmọ́ àwọn ìdí kan wà tí kò fi bẹ́ẹ̀ bọ́gbọ́n mu. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀dọ́kùnrin kan tó ń jẹ́ Mario gbà bẹ́ẹ̀, ó ní, “Torí pé mo fẹ́ sá fáwọn ojúṣe mi nínú ilé ni mo ṣe fẹ́ kó kúrò ńlé.”

 Ṣó o fẹ́ gbọ́, ó ṣeé ṣe kí òmìnira tó o ní dín kù tó o bá kúrò nílé. Onya tó jẹ́ ọmọ ọdún méjìdínlógún (18) sọ pé, “Tó o bá ti kúrò ńlé, ìwọ ni wàá máa tọ́jú ilé ẹ fúnra ẹ, ìwọ ni wàá máa dáná fúnra ẹ, tí wàá sì máa sanwó tibí sanwó tọ̀hún. Kò ní sí pé àwọn òbí ẹ ń bá ẹ fọwọ́ kún un!”

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Ó yẹ kó o mọ ìdí tó o fi fẹ́ kúrò nílé kó o lè mọ̀ bóyá o ti tó ẹni tó ń kúrò nílé.

 Rò ó dáadáa

 Jésù sọ pé: “Ta ni nínú yín tí ó fẹ́ kọ́ ilé gogoro kan tí kò ní kọ́kọ́ jókòó, kí ó sì gbéṣirò lé ìnáwó náà, láti rí i bí òun bá ní tó láti parí rẹ̀?” (Lúùkù 14:28) Báwo lo ṣe lè “gbéṣirò lé ìnáwó náà” tó bá dọ̀rọ̀ kíkó kúrò ńlé? Yẹ ara ẹ wò lórí àwọn kókó yìí.

ṢÉ ỌMỌLÚÀBÍ NI Ẹ́ TÓ BÁ DỌ̀RỌ̀ KÁ NÁWÓ?

 Bíbélì sọ pé: “Owó . . . jẹ́ fún ìdáàbòbò.”​​—Oníwàásù 7:​12.

  •  Ṣó máa ń ṣòro fún ẹ láti fowó pa mọ́?

  •  Ṣé yànfùyànfù lo máa ń náwó?

  •  Ṣé o sábà máa ń yáwó lọ́wọ́ àwọn míì?

 Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo dáhùn sí ìkankan nínú àwọn ìbéèrè yìí, a jẹ́ pé tó o bá lọ ń dá gbé, bóyá ni àbámọ̀ ò ní gbẹ̀yìn ọ̀rọ̀ ẹ!

 “Ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún (19ni ẹ̀gbọ́n mi nígbà tí wọ́n kúrò ńlé. Láàárín ọdún kan, wọ́n ti ná gbogbo owó tí wọ́n ń tọ́jú tán, báǹkì gbẹ́sẹ̀ lé mọ́tò wọn, wọn ò yá wọn lówó mọ́ torí wọ́n ti ba orúkọ ara wọn jẹ́; wọ́n wá ń bẹ̀ wá pé ká jẹ́ káwọn má pa dà bọ̀ nílé.”​​—Danielle.

 Ohun tó o lè ṣe báyìí: Bi àwọn òbí ẹ léèrè iye tí wọ́n sábà máa ń ná lóṣù kan. Àwọn nǹkan wo ni wọ́n máa ń sanwó fún, báwo sì ni wọ́n ṣe ń ṣètò iye tó ń wọlé fún wọn kí wọ́n lè kájú ìnáwó wọn? Báwo ni wọ́n ṣe ń fowó pa mọ́?

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá kọ́ bó o ṣe lè náwó ní báyìí tó o ṣì wà nílé, ó máa jẹ́ kó o mọ bí wàá ṣe máa forí rọ́ ìṣòro ìnáwó tó o bá ti ń dá gbé.

ṢÉ O MÁA Ń KÓRA Ẹ NÍJÀÁNU?

 Bíbélì sọ pé: “Olúkúlùkù ni yóò ru ẹrù ti ara rẹ̀.”​—Gálátíà 6:5.

  •  Ṣé o máa ń fòní dónìí fọ̀la dọ́la?

  •  Ṣé ó dìgbà táwọn òbí ẹ bá tó rán ẹ létí iṣẹ́ tó yẹ kó o ṣe kó o tó ṣe é?

  •  Tó o bá jáde, ṣé o máa ń kọjá aago tí àwọn òbí ẹ bá dá fún ẹ pé kó o délé?

 Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo dáhùn sí ìkankan nínú àwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe kó túbọ̀ nira fún ẹ láti máa hùwà ọmọlúàbí tó o bá ti ń dá gbé.

 “Tó o bá ti dá wà, àwọn nǹkan kan wà tó jẹ́ pé kì í ṣe pó máa ń wù ẹ́ ṣe, àmọ́ o gbọ́dọ̀ wáyè fún un. Kò sẹ́ni tó máa sọ fún ẹ pé kó o ṣe àwọn nǹkan yẹn, àfi kó o ní in lọ́kàn pé o gbọ́dọ̀ ṣe é, kó o sì ṣètò bí wàá ṣe máa ṣe é déédéé.”​—Jessica.

 Ohun tó o lè ṣe báyìí: Fún odindi oṣù kan, gbìyànjú láti rí i pé o ṣe oríṣiríṣi iṣẹ́ nínú ilé yín, bó bá ṣe lè pọ̀ tó. Bí àpẹẹrẹ, tọ́jú inú ilé fúnra ẹ, ìwọ ni kó o fọ aṣọ ẹ, lọ sọ́jà, máa dáná lálaalẹ́, kó o sì fọ abọ́ tẹ́ ẹ bá jẹun tán. Èyí máa jẹ́ kó o rí bí nǹkan ṣe máa rí tó o bá ti ń dá gbé.

 Òótọ́ ibẹ̀ ni pé: Tó o bá fẹ́ máa dá gbé láyè ara ẹ, ó ṣe pàtàkì kó o máa kóra ẹ níjàánu.

Téèyàn bá kó kúrò ńlé láìmúra sílẹ̀, ṣe ló dà bí ẹni bẹ́ jáde látinú ọkọ̀ òfuurufú láìkọ́kọ́ kọ́ bí wọ́n ṣe ń lo ohun tí wọ́n fi ń fò lójú òfuurufú

ṢÉ O MÁA Ń LÈ KÁPÁ ÌMỌ̀LÁRA Ẹ?

 Bíbélì sọ pé: “Ẹ mú gbogbo wọn kúrò lọ́dọ̀ yín, ìrunú, ìbínú, ìwà búburú, ọ̀rọ̀ èébú . . . kúrò.”​—Kólósè 3:8.

  •  Ṣé ó máa ń nira fún ẹ láti bá àwọn míì da nǹkan pọ̀?

  •  Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti kápá ìbínú ẹ?

  •  Ṣé ohun tí ìwọ bá ṣáà ti fẹ́ lo máa ń fẹ́ káwọn míì ṣe ṣáá?

 Tó bá jẹ́ pé bẹ́ẹ̀ ni lo dáhùn sí ìkankan nínú àwọn ìbéèrè yìí, ó ṣeé ṣe kó o níṣòro tó o bá ń bá ọ̀rẹ́ rẹ míì gbé, ohun kan náà ló sì máa ṣẹlẹ̀ tó bá yá tó o bá ṣègbéyàwó.

 “Ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn míì gbé ni kùdìẹ̀kudiẹ mi fara hàn. Mo rí i pé kò yẹ kí n máa retí kí àwọn míì ní àmúmọ́ra témi bá ń kanra torí pé ó ti rẹ̀ mí. Àfi kí n wá ọgbọ́n míì dá sí i tí mi ò fi ní pa àwọn míì lára.”​—Helena.

 Ohun tó o lè ṣe báyìí: Kọ́ bí ìwọ àtàwọn òbí ẹ pẹ̀lú àwọn àbúrò àti ẹ̀gbọ́n ẹ á ṣe máa gbọ́ra yín yé. Ó ṣe tán, bó o bá ṣe ṣe sáwọn tẹ́ ẹ jọ ń gbé báyìí tí wọ́n bá ṣàṣìṣe máa pinnu bó o ṣe máa ṣe sí ẹnikẹ́ni tẹ́ ẹ bá jọ gbé lọ́jọ́ iwájú.

 Òtítọ́ ibẹ̀ ni pé: Dídágbé láyè ara ẹni kì í ṣe ohun téèyàn lè fi kẹ́wọ́ torí pé ó ń sá fún ojúṣe, ohun tó gba kéèyàn múra sílẹ̀ ni. O ò ṣe bá àwọn tó ti ṣe irú ẹ̀ yọrí sọ̀rọ̀? Bi wọ́n pé, ká sọ pé wọ́n láǹfààní ẹ̀ lẹ́ẹ̀kejì, kí làwọn ohun tí wọn ì bá ṣe tàbí kí wọ́n má ṣe, tàbí kí lohun tó wù wọ́n kí wọ́n mọ̀ nígbà yẹn tí wọn ò mọ̀, àmọ́ tí wọ́n ti mọ̀ báyìí? Ó dáa kéèyàn gbé irú ìgbésẹ̀ yẹn tó bá fẹ́ ṣe ìpinnu pàtàkì èyíkéyìí!