ẸNÌ KAN LÈ RÀN Ẹ́ LỌ́WỌ́ LÁTI KẸ́KỌ̀Ọ́ BÍBÉLÌ
Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!
Wàá gbádùn ìjíròrò Bíbélì yìí gan-an, ọ̀fẹ́ ni, wàá sì rí ìdáhùn àwọn ìbéèrè bíi:
Báwo ni mo ṣe lè láyọ̀?
Ṣé ìwà ibi àti ìyà lè dópin?
Ṣé màá pa dà rí àwọn èèyàn mi tó ti kú?
Ṣé Ọlọ́run bìkítà nípa mi?
Báwo ni mo ṣe lè gbàdúrà lọ́nà táá mú kí Ọlọ́run gbọ́ àdúrà mi?
Ọ̀fẹ́ Ni
Ọ̀fẹ́ ni ìkẹ́kọ̀ọ́ náà, títí kan ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! tá a máa lò. A tún máa fún ẹ ní Bíbélì tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀.
Ó Rọrùn Gan-an
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa kàn sí ẹ látorí ẹ̀rọ, ó sì lè wá bá ẹ níbi tó o bá fẹ́ àti nígbà tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn.
A ò ní fi dandan mú ẹ
Ìgbàkigbà lo lè pinnu pé o ò ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà mọ́, a ò ní fi dandan mú ẹ.
Báwo la ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì?
Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́kọ̀ọ̀kan. Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé! wàá máa lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni díẹ̀díẹ̀, wàá sì rí bó o ṣe lè máa fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i, wo fídíò yìí tàbí kó o ṣàyẹ̀wò ìbéèrè táwọn èèyàn máa ń béèrè nípa ìkẹ́kọ̀ọ́ náà.
Ṣé wàá fẹ́ mọ bí ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe rí?
Wo ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú ìwé náà.
Ṣé wàá gbìyànjú ẹ̀ báyìí?
Tẹ bọ́tíìnì yìí kó o lè ṣètò ìgbà tó máa rọ̀ ẹ́ lọ́rùn láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.