Báwo Ni Mo Ṣe Lè Di Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
Jésù ṣàlàyé ohun tó yẹ kéèyàn ṣe kó tó lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ohun tó sọ sì wà nínú ìwé Mátíù 28:19, 20. Àwọn ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ ohun tó yẹ kí ẹnì kan ṣe kó tó lè di ọmọlẹ́yìn Jésù. Lára ẹ̀ ni kó máa sọ̀rọ̀ tàbí kó máa jẹ́rìí nípa Jèhófà.
Ohun Àkọ́kọ́: Kẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n “sọ àwọn ènìyàn . . . di ọmọ ẹ̀yìn,” kí wọ́n “máa kọ́ wọn.” (Mátíù 28:19, 20) Lédè Gíríìkì, ohun tí ọ̀rọ̀ tí wọ́n tú sí “ọmọ ẹ̀yìn” túmọ̀ sí ni “akẹ́kọ̀ọ́.” Nínú Bíbélì, wàá rí àwọn ohun tí Jésù fi kọ́ni tó máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ kí ìgbésí ayé rẹ lè nítumọ̀, kó o sì lè láyọ̀. (2 Tímótì 3:16, 17) Inú wa máa dùn láti bá ẹ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, kó o lè mọ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni.—Mátíù 10:7, 8; 1 Tẹsalóníkà 2:13.
Ohun Kejì: Fi ohun tó ò ń kọ́ sílò. Jésù tún sọ pé kí àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ‘máa pa gbogbo ohun tí òun pa láṣẹ mọ́.’ (Mátíù 28:20) Ìyẹn fi hàn pé kì í ṣe torí kó o kàn lè lóye àwọn ẹ̀kọ́ tó díjú ló ṣe yẹ kó o kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ṣe pàtàkì kó o jẹ́ kí ohun tó ò ń kọ́ máa nípa lórí bó o ṣe ń ronú àti ìwà tó ò ń hù, kó o lè ṣe ìyípadà tó yẹ. (Ìṣe 10:42; Éfésù 4:22-29; Hébérù 10:24, 25) Àwọn tó bá ń ṣe ohun tí Jésù sọ máa wá ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, ìyẹn ni pé wọ́n á pinnu látọkàn wá láti máa tẹ̀ lé Jésù.—Mátíù 16:24.
Ohun Kẹta: Ṣe ìrìbọmi. (Mátíù 28:19) Bíbélì fi ẹni tó ṣe ìrìbọmi wé ẹni tó kú, tí wọ́n wá sin. (Fi wé Róòmù 6:2-4.) A fi wé ikú torí ẹni tó bá ṣèrìbọmi ti jáwọ́ nínú àwọn ìwà tí ò dáa tó ń hù tẹ́lẹ̀, ó sì ti bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà tó dáa. Torí náà, tó o bá ṣèrìbọmi, ṣe lò ń fi hàn ní gbangba pé o ti ṣe ohun méjì àkọ́kọ́ tí Jésù sọ, o sì ń bẹ Ọlọ́run pé kó jẹ́ kó o ní ẹ̀rí ọkàn tó mọ́.—Hébérù 9:14; 1 Pétérù 3:21.
Báwo ni màá ṣe mọ̀ tí mo bá tóótun láti ṣe ìrìbọmi?
Bá àwọn alàgbà ìjọ sọ̀rọ̀. Tẹ́ ẹ bá ti jọ sọ̀rọ̀, wọ́n á mọ̀ bóyá o mọ ohun tó túmọ̀ sí láti ṣèrìbọmi, bóyá ò ń fi ohun tó ò ń kọ́ ṣèwà hù, wọ́n á sì mọ̀ bóyá o ti ya ara rẹ sí mímọ́ fún Ọlọ́run látọkàn wá.—Ìṣe 20:28; 1 Pétérù 5:1-3.
Ǹjẹ́ àwọn ọmọ tí òbí wọn jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà máa ṣe àwọn ohun tá a mẹ́nu bà yìí?
Bẹ́ẹ̀ ni. À ń tọ́ àwọn ọmọ wa “nínú ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” bí Bíbélì ṣe ní ká ṣe. (Éfésù 6:4) Àmọ́ bí wọ́n ṣe ń dàgbà, wọ́n gbọ́dọ̀ pinnu lọ́kàn wọn pé àwọn máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kí wọ́n gbà pé òótọ́ lohun táwọn ń kọ́, kí wọ́n sì máa fi ṣèwà hù kí wọ́n tó lè ṣèrìbọmi. (Róòmù 12:2) Kókó ibẹ̀ ni pé, kálukú ló máa pinnu ohun tó máa ṣe tó bá di ọ̀rọ̀ ìjọsìn.—Róòmù 14:12; Gálátíà 6:5.