Ṣé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun Péye?
Ọdún 1950 ni wọ́n mú apá àkọ́kọ́ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun jáde. Látìgbà yẹn ni àwọn èèyàn ti ń sọ̀rọ̀ dáadáa nípa Bíbélì náà. Àmọ́ àwọn míì ń kọminú pé bóyá ni Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun a péye, torí pé láwọn ibì kan ó yàtọ̀ sáwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì. Àwọn kókó tá a tò sísàlẹ̀ yìí ló sábà máa ń fa àwọn ìyàtọ̀ yẹn.
Ìsọfúnni tá a lò. Ìwádìí tó péye táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ṣe àtàwọn ìwé àfọwọ́kọ tó ṣe é fọkàn tán la fi túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Èyí yàtọ̀ sí ìtumọ̀ Bíbélì King James Version ti ọdún 1611 torí pé àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí kò péye, tí ọjọ́ rẹ̀ kò sì pẹ́ tó èyí tí wọ́n fi túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ni wọ́n lò.
Ìtumọ̀ tó ṣe rẹ́gí. Àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sapá láti rí i pé ìtumọ̀ wọn bá ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí mu wẹ́kú. (2 Tímótì 3:16) Ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì ló yí àwọn ọ̀rọ̀ kan pa dà kó lè bá èrò tiwọn mu. Àpẹẹrẹ kan ni bí wọ́n ṣe yọ orúkọ Ọlọ́run ìyẹn, Jèhófà, tí wọ́n sì fi àwọn orúkọ oyè bí Olúwa àti Ọlọ́run rọ́pò rẹ̀.
Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ tó kún rẹ́rẹ́. Kàkà kí wọ́n kàn túmọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì lóréfèé, ńṣe ni àwọn tó túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sapá láti ri pé wọ́n tú àwọn ọ̀rọ̀ náà ní ṣangiliti bó ṣe wà nínú Bíbélì. Síbẹ̀, wọ́n rí i dájú pé ìtumọ̀ náà ṣe kedere, kò sì rí gbágungbàgun. Àmọ́, àwọn atúmọ̀ Bíbélì míì tí wọ́n kàn ṣètumọ̀ lóréfèé máa ń fi èrò wọn kún ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tàbí kí wọ́n sọ àwọn ìsọfúnni pàtàkì kan nù.
Ìyàtọ̀ tó wà láàárín Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àtàwọn ìtumọ̀ táwọn míì ṣe
Àwọn ìwé tí kò sí nínú Bíbélì. Ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì àti Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti Ìlà Oòrùn fi ìwé táwọn kan ń pè ní Àpókírífà kún Bíbélì wọn. Àmọ́, ìwé yìí kò sí lára àkójọ ìwé àwọn Júù tó para pọ̀ di Bíbélì. Bíbélì sì sọ pé àwọn Júù ni a “fi àwọn ọ̀rọ̀ ìkéde ọlọ́wọ̀ ti Ọlọ́run sí ìkáwọ́ wọn.” (Róòmù 3:1, 2) Torí náà, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun àti ọ̀pọ̀ àwọn Bíbélì òde òní kò fi ìwé Àpókírífà kún Bíbélì wọn.
Awọn ẹsẹ tí kò sí nínú Bíbélì. Àwọn atúmọ̀ Bíbélì kan fi àwọn ọ̀rọ̀ àti ẹsẹ tí kò sí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ kún Bíbélì wọn. Àmọ́, wọn kò fi àwọn àfikún yìí sínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun. Ọ̀pọ̀ àwọn ìtumọ̀ Bíbélì òde òní kò ní àwọn àfikún yìí, torí kò sí nínú Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀. b
Ìtumọ̀ tó ṣe kedere. Lọ́pọ̀ ìgbà, títúmọ̀ ẹyọ ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan máa ń mú kí àlàyé díjú tàbí kó ṣòro lóye. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù nínú Mátíù 5:3 sí: “Alábùkún-fún ni àwọn òtòṣì ní ẹ̀mí.” (English Standard Version; King James Version; New International Version) Ọ̀rọ̀ náà “òtòṣì ní ẹ̀mí” ṣòro lóye fún ọ̀pọ̀ èèyàn, àwọn míì sì rò pé ńṣe ni Jésù ń sọ àǹfààní tá a máa rí tá a bá jẹ́ ẹlẹ́mìí ìrẹ̀lẹ̀ tàbí òtòṣì. Àmọ́, ohun tí Jésù ń sọ ni pé èèyàn máa ní ayọ̀ tòótọ́ tó bá ń wá ìtọ́sọ́nà Ọlọ́run. Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun gbé ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ náà yọ lọ́nà tó péye, ó sọ pé “àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn”—Mátíù 5:3. c
Ọ̀rọ̀ dáadáa táwọn ọ̀mọ̀wé tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ nípa Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun
Ọ̀mọ̀wé Bíbélì kan tó ń jẹ́ Edgar J. Goodspeed kọ lẹ́tà kan ní December 8, 1950, nípa Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun pé: “Inú mi dùn sí iṣẹ́ takuntakun tí àwọn èèyàn yín ń ṣe, àti bó ṣe ń tàn káàkiri ayé, inú mi tún wá dùn gan-an sí ìtumọ̀ tó yọ̀ mọ́ni lẹ́nu, tó ṣe ṣàkó, tó sì ṣe kedere tẹ́ ẹ ṣe. Ó fi hàn pé ẹ ti wádìí jinlẹ̀ dáadáa kí ẹ tó mú un jáde.”
Ọ̀jọ̀gbọ́n Allen Wikgren ti yunifásítì ìlú Chicago sọ nípa Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun pé, ó jẹ́ àpẹẹrẹ Bíbélì tó lo èdè lọ́ọ́lọ́ọ́ àti pé, Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ ni wọ́n fi túmọ̀ rẹ̀ kì í ṣe àwọn ìtumọ̀ Bíbélì tó ṣáájú, èyí mú kí àwọn ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ ṣe kedere.”—The Interpreter’s Bible, Apá kìíní, ojú ìwé 99.
Alexander Thomson tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Ìwé Mímọ́ Kristian Lédè Griki ní Ìtumọ̀ Ayé Titun, ó ní: “Ẹ̀rí fi hàn kedere pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀, tí wọ́n já fáfá, tí wọ́n sì kún fún làákàyè, ni wọ́n túmọ̀ ìwé yìí. Wọ́n sì tún gbìyànjú láti mú ohun tí ọ̀rọ̀ Gíríìkì túmọ̀ sí gan-an jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì.”—The Differentiator, April 1952, ojú ìwé 52.
Láìka pé òǹkọ̀wé Francis Potter tọ́ka sí àwọn nǹkan tó rú u lójú nínú Bíbélì náà, ó sọ pé: “Ògbóǹkangí ọ̀mọ̀wé làwọn tó túmọ̀ Bíbélì yìí, iṣẹ́ ọpọlọ gbáà ni wọ́n ṣe láti túmọ̀ èdè Gíríìkì àti Hébérù lọ́nà tó dára jù.”—The Faiths Men Live By, ojú ìwé 300.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Robert M. McCoy gbà pé Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ní ibi tó dáa sí àti ibi tó kù sí, síbẹ̀ ó sọ pé: “Ìtumọ̀ Májẹ̀mú Tuntun yìí fi hàn pé àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ wà nínú ìjọ [àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà], àwọn tó lè fi òye yanjú ọ̀pọ̀ ìṣòro tó wà nínú iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì.”—Andover Newton Quarterly, January 1963, ojú ìwé 31.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀jọ̀gbọ́n S. MacLean Gilmour kò fara mọ́ bí wọ́n ṣe túmọ̀ àwọn ibi kan nínú Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, síbẹ̀ ó gbà pé àwọn tó túmọ̀ rẹ̀ “lóye èdè Gíríìkì dáadáa.”—Andover Newton Quarterly, September 1966, ojú ìwé 26.
Nínú àyẹ̀wò tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Thomas N. Winter ṣe lórí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà lára Bíbélì Kingdom Interlinear Translation of the Greek Scriptures, ó sọ pé: “Ìtumọ̀ táwọn atúmọ̀ èdè tí kò polongo ara wọn yìí ṣe bóde mu, ó sì péye délẹ̀délẹ̀.”—The Classical Journal, April-May 1974, ojú ìwé 376.
Ọ̀jọ̀gbọ́n Benjamin Kedar-Kopfstein tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé nínú èdè Hébérù lórílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì sọ ní ọdún 1989 pé: “Nínú ìwádìí tí mo ṣe nípa Bíbélì èdè Hébérù àti ìtumọ̀ rẹ̀, mo sábà máa ń tọ́ka sí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tó wà lédè Gẹ̀ẹ́sì. Bí mo ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀ jẹ́ kó túbọ̀ dá mi lójú pé àwọn to túmọ̀ Bíbélì yìí sapá gidigidi láti rí i pé a lóye Ìwé Mímọ́ lọ́nà tó péye.”
Jason David BeDuhn tó jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìsìn ṣe àyẹ̀wò oríṣi ìtumọ̀ Bíbélì mẹ́sàn-án lédè Gẹ̀ẹ́sì, ó wá sọ pé: “Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ló péye jù lọ nínú gbogbo àwọn tóun yẹ̀ wò.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ èèyàn rò pé ojúsàájú táwọn tó túmọ̀ Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ṣe ló mú kí Bíbélì náà yàtọ̀ sáwọn ìtumọ̀ míì, BeDuhn sọ pé: “Ohun tó mú kí Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun yàtọ̀ ni pé, ó péye gan-an, ọ̀rọ̀ tí wọ́n lò nínú rẹ̀ bá ohun tó wà nínú Májẹ̀mú Tuntun ti ìpilẹ̀ṣẹ̀ mu.”—Truth in Translation, ojú ìwé 163, 165.
a Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun lédè Gẹ̀ẹ́sì tá a tẹ̀ jáde ṣáájú ti ọdún 2013 ni àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.
b Bí àpẹẹrẹ, tó o bá wo Bibeli New International Version àti New Jerusalem Bible tí àwọn Kátólíìkì ṣe, wà á rí àwọn àfikún ẹsẹ Bíbélì náà. Irú bíi Mátíù 17:21; 18:11; 23:14; Máàkù 7:16; 9:44, 46; 11:26; 15:28; Lúùkù 17:36; 23:17; Jòhánù 5:4; Ìṣe 8:37; 15:34; 24:7; 28:29; àti Róòmù 16:24. Bíbélì King James Version àti Bíbélì Douay-Rheims Version ṣe àfikún tó gbé ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan lárugẹ sí 1 Jòhánù 5:7, 8. Ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún lẹ́yìn tí wọ́n kọ Bíbélì ni àfikún yìí yọ́ wọlé.
c Bákan náà, ìtumọ̀ Bíbélì ti J. B. Phillips’ túmọ̀ ọ̀rọ̀ Jésù yẹn sí “àwọn tó mọ̀ pé àwọn nílò Ọlọ́run.” Bákan náà, Bíbélì The Translator’s New Testament túmọ̀ rẹ̀ sí “àwọn tó mọ àìní wọn nípa tẹ̀mí.”