Kí Ni Watch Tower Bible and Tract Society?
Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania ni àjọ tí kì í ṣe fún ìṣòwò tí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá sílẹ̀ lábẹ́ òfin àjọ Commonwealth of Pennsylvania ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà lọ́dún 1884. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà là ń lo àjọ yìí láti fi ti iṣẹ́ tí à ń ṣe kárí ayé lẹ́yìn, tó ní nínú títẹ Bíbélì àti àwọn ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Ìdí tí a fi dá àjọ yìí sílẹ̀ bó ṣe wà nínú ìwé àṣẹ ìjọba jẹ́ torí “ìjọsìn, ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá.” Ní pàtàkì jù lọ, à ń lo àjọ yìí láti “kọ́ àwọn èèyàn ká sì wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù Kristi máa ṣàkóso rẹ̀.” Kì í ṣe bí èèyàn bá ṣe dáwó tó la fi ń yan àwọn tó máa wà nínú àjọ yìí, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe la máa ń fìwé pe àwọn tó máa wà níbẹ̀. Àwọn tó wà nínú àjọ yìí àtàwọn alábòójútó rẹ̀ máa ń ran Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́wọ́.
Àwọn Àjọ Tá A Dá Sílẹ̀ Lábẹ́ Òfin
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ àjọ tá a dá sílẹ̀ lábẹ́ òfin ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè yàtọ̀ sí àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Watch Tower” tàbí “Watchtower” máa ń wà lára orúkọ àwọn kan lára àjọ tá a dá sílẹ̀ yìí tàbí kí wọ́n tú àwọn ọ̀rọ̀ yìí sínú orúkọ tí wọn lò lábẹ́ òfin.
Àwọn onírúurú àjọ tí à ń lò yìí ti jẹ́ ká lè ṣe ọ̀pọ̀ àṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ wa látìgbà tá a ti dá wọn sílẹ̀, díẹ̀ lára ohun tá a ti ṣe láṣeyọrí nìyí:
Ìwé kíkọ àti ìwé títẹ̀. A ti tẹ nǹkan bí igba ó lé ogun [220] mílíọ̀nù Bíbélì àti àwọn ìwé tá a fi ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ogójì [40] bílíọ̀nù ní èdè tó lé ní ẹgbẹ̀rún dín ọgọ́rún-ún [900]. Ìkànnì jw.org/yo ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lè ka Bíbélì lórí íńtánẹ́ẹ̀tì lọ́fẹ̀ẹ́ ní èdè tó lé ní ọgọ́jọ [160], kí wọ́n sì rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè Bíbélì, irú bíi “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?”
Ètò ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Oríṣiríṣi ilé ẹ̀kọ́ la ní tí a ti máa ń dá àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, bẹ̀rẹ̀ láti ọdún 1943, Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] ló ti jàǹfààní nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, èyí sì ti mú kí wọ́n lè máa sìn bíi Míṣọ́nárì tàbí kí wọ́n sìn níbi tí wọ́n á ti lè mú kí iṣẹ́ náà fìdí múlẹ̀ kó sì máa tẹ̀ síwájú kárí ayé. Ọ̀pọ̀ èèyàn títí kan àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń dara pọ̀ láti gba ìtọ́ni lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láwọn ìpàdé wa. Yàtọ̀ síyẹn, a máa ń lo ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tá a tẹ̀ ní èdè tó tó ọgọ́fà [120] láti fi kọ́ àwọn tí kò mọ̀wé kọ tàbí mọ̀ọ́kà.
Ṣíṣèrànwọ́ fún àwọn tí àjálù dé bá. A ti pèsè àwọn ohun ìgbẹ́mìíró fún àwọn èèyàn tí àjálù dé bá, bóyá àjálù yẹn jẹ́ àfọwọ́fà irú ogun kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà tó ṣẹlẹ̀ lórílẹ̀-èdè Rwanda lọ́dún 1994 tàbí èyí tó kàn ṣàdédé ṣẹlẹ̀ irú bí ìmìtìtì ilẹ̀ tó wáyé lórílẹ̀-èdè Haiti lọ́dún 2010.
Àwọn àjọ yìí ti mú kí iṣẹ́ wa gbòòrò sí i lóòótọ́, àmọ́ kò túmọ̀ sí pé a ò lè dá nǹkan kan ṣe láìsí àwọn àjọ yìí. Iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé gbogbo àwa Kristẹni lọ́wọ́ ni láti kọ́ àwọn èèyàn kí a sì wàásù ìhìn rere, ojúṣe gbogbo àwa Kristẹni lẹ́nìkọ̀ọ̀kan sì ni èyí jẹ́. (Mátíù 24:14; 28:19, 20) A gbà pé Ọlọ́run ló ń ti iṣẹ́ wa lẹ́yìn, yóò sì “mú kí ó máa dàgbà.”—1 Kọ́ríńtì 3:6, 7.