Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì

A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.

A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.

Mozambique

Rua da Micaia No. 160

Bairro Triunfo

Costa do Sol

MAPUTO

MOZAMBIQUE

+258 21-450-500

Wíwo Ọgbà Wa Yíká

Monday sí Friday

8:00 àárọ̀ sí 11:00 àárọ̀ àti 1:00 ọ̀sán sí 3:30 ọ̀sán

Ó máa gba wákàtí kan

Àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe níbẹ̀

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa lórílẹ̀-èdè Mozambique ń bójú tó iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí iye wọn jẹ́ 87,668 ń ṣe. Wọ́n ń túmọ̀ àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì sí nǹkan bí ogún [20] èdè níbẹ̀, wọ́n sì ń kó o ránṣẹ́ sí ìjọ 1,651 jákèjádò orílẹ̀-èdè náà. A máa ń sọ ìtàn àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Mozambique ní ṣókí fún àwọn tó bá wá wo ọgbà wa.

Wa ìwé pẹlẹbẹ tó ń ṣàlàyé nípa ẹ̀ka ọ́fíìsì wa jáde.