Ìbẹ̀wò sí Bẹ́tẹ́lì
A rọ̀ ẹ́ pé kó o wá ṣèbẹ̀wò sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Bẹ́tẹ́lì la sábà máa ń pe àwọn ibí yìí. Àwọn kan lára àwọn ọ́fíìsì yìí ní àwọn àtẹ téèyàn lè wò fúnra ẹ̀.
A Lè Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Ṣèbẹ̀wò Pa Dà: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àti June 1, 2023 làwọn èèyàn ti láǹfààní láti ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa. Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni sí i, kàn sí ẹ̀ka ọ́fíìsì tí wàá fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí. Jọ̀wọ́, má ṣe wá fún ìbẹ̀wò tí àyẹ̀wò bá fi hàn pé ó ní àrùn Kòrónà, tàbí tó ń ṣe ẹ́ bí òtútù tàbí ibà, tàbí tó o wà pẹ̀lú ẹnì kan tí àyẹ̀wò fi hàn pé ó ní àrùn náà.
United States
Ìbẹ̀wò sí Ẹ̀ka Ọ́fíìsì
Ṣó yẹ kéèyàn sọ ṣáájú kó tó ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó yẹ. A fẹ́ kí gbogbo ẹni tó fẹ́ ṣèbẹ̀wò sí bẹ́tẹ́lì kọ́kọ́ sọ fún wa ṣáájú kí wọ́n tó máa bọ̀, yálà àwọn tó ń bọ̀ pọ̀ tàbí wọn ò tó nǹkan ìdí sì ni pé a ò fẹ́ kí èrò pọ̀ jù, a sì fẹ́ kí gbogbo ẹni tó wá gbádùn ìbẹ̀wò wọn.
Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ṣé ẹ ṣì lè ṣèbẹ̀wò sí ẹ̀ka ọ́fíìsì? Tẹ́ ò bá sọ fún wa ṣáájú, ó ṣeé ṣe ká má gbà yín láyè láti rìn yíká ọgbà wa. Ìdí sì ni pé ó níye èèyàn tá a lè mú rìn yíká ọgbà wa lójúmọ́.
Ìgbà wo ló yẹ kẹ́ ẹ dé? Kérò má bàa pọ̀ jù, ẹ jọ̀wọ́, ẹ dé ní ó kéré tán, wákàtí kan kó tó di pé wọ́n máa mú yín rìn yíká.
Báwo lẹ ṣe máa sọ fún wa ṣáájú? Tí iye ẹ̀yin tẹ́ ẹ̀ ń bọ̀ kò bá ju ogún lọ, tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò—A Ò Ju Ogún (20) Lọ.” Tẹ́ ẹ bá ju ogún lọ, tẹ bọ́tìnì “Ṣàdéhùn Ọjọ́ Ìbẹ̀wò—Iye Wa Jẹ́ Ogun (20) Tàbí Jù Bẹ́ẹ̀ Lọ.”
Ṣé ẹ lè yí ọjọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá pa dà tàbí kẹ́ ẹ sọ pé ẹ ò ní lè wá mọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Tẹ bọ́tìnì tá a pè ní “Wo Ọjọ́ Àdéhùn Tàbí Kó O Yí I Pa Dà.”
Tó bá ṣẹlẹ̀ pé kò sí àyè mọ́ lọ́jọ́ tẹ́ ẹ fẹ́ wá ńkọ́? Ẹ máa wo ìkànnì wa látìgbàdégbà. Àyè máa yọ táwọn kan bá yí ọjọ́ tí wọ́n fẹ́ wá pa dà tàbí tí wọn ò fẹ́ wá mọ́.
Ìbẹ̀wò
Warwick
1 Kings Dr.
TUXEDO PARK, NY 10987
UNITED STATES
+1 845-524-3000
Àwọn iṣẹ́ tí à ń ṣe níbẹ̀
Àwọn Àtẹ Téèyàn Lè Wo Fúnra Ẹ̀
Bíbélì àti Orúkọ Àtọ̀runwá Náà. Àwọn Bíbélì tí kò fi bẹ́ẹ̀ wọ́pọ̀ ló wà níbi àtẹ yìí, ó sì jẹ́ kó ṣe kedere pé orúkọ Ọlọ́run ṣì wà nínú Bíbélì láìka bí àwọn èèyàn ṣe gbìyànjú láti yọ orúkọ náà kúrò. Àtẹ tó ń yí kan tún wà níbẹ̀ tó ní àwọn Bíbélì tó ṣọ̀wọ́n míì àti àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé nípa Bíbélì.
Àwọn Èèyàn Kan fún Orúkọ Jèhófà. Àtẹ yìí sọ ìtàn bí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe gbèrú nínú ìjọsìn wa. Ẹ máa rí àwọn àwòrán, àwọn ohun ìṣẹ̀ǹbáyé àti ọ̀rọ̀ látẹnu àwọn tí gbogbo ẹ̀ ṣojú wọn tó ń fi bí Jèhófà ṣe ń darí àwọn èèyàn rẹ̀ ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé hàn, tó ń kọ́ wọn, tó sì ń ṣètò wọn kí wọ́n lè ṣe ìfẹ́ rẹ̀.
Ìgbàgbọ́ ní Oríléeṣẹ́. Àtẹ yìí ṣàlàyé iṣẹ́ àwọn ìgbìmọ̀ kéékèèké tí Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń lò, ìyẹn ohun tí wọ́n ṣe kí àwọn èèyàn Jèhófà lè máa pàdé pọ̀, kí wọ́n lè máa sọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n lè máa róúnjẹ tẹ̀mí jẹ, kí wọ́n sì máa fìfẹ́ hàn síra wọn.
Àwọn Ibi Tí Wọ́n Máa Mú Yín Dé
Wọ́n máa mu yín rìn yí ká àwọn ọ́fíìsì àti ibí tá a ti ń bójú tó ọgbà Warwick.
Patterson
100 Watchtower Dr. (2891 Route 22)
PATTERSON, NY 12563
UNITED STATES
+1 845-306-1000
Àwọn Iṣẹ́ Tí À Ń Ṣe Níbẹ̀
A máa ń ṣe àwọn àwòrán tí à ń lò nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa, bákan náà la máa ń ṣe fídíò àti àwọn àtẹ́tísí lóríṣiríṣi. Àwọn tó bá wá ṣèbẹ̀wò á rí oríṣiríṣi àwọn ilé-ẹ̀kọ́ Bíbélì tí á ń ṣe níbí.
Wallkill
900 Red Mills Rd.
WALLKILL, NY 12589
UNITED STATES
+1 845-744-6000
Àwọn Iṣẹ́ Tí À Ń Ṣe Níbẹ̀
À ń tẹ Bíbélì tó tó mílíọ̀nù mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25 million) lọ́dọọdún ní èdè tó jú ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti ọgọ́ta (360) a sì ń kó wọn ránṣẹ́ sí àwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì wa kárí ayé. A tún ń ṣe bẹ́ẹ̀ fún àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ní Amẹ́ríkà, Kánádà àti Caribbean.