Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà Gbọ́ Tuntun Níbi tí Wọ́n Ti Ń Ṣayẹyẹ Nílùú New York

Àwọn Ọmọ Ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà Gbọ́ Tuntun Níbi tí Wọ́n Ti Ń Ṣayẹyẹ Nílùú New York

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa ń rò pé àwọn abúlé ilẹ̀ Amẹ́ríkà ni ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà ń gbé. Òótọ́ ibẹ̀ ní pé èyí tó ju ìdajì lọ lára àwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà ló ń gbé nígboro. Ìlú tó tóbi jù lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ìyẹn ìlú New York ni wọ́n ti ṣayẹyẹ àrà ọ̀tọ̀ táwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà máa ń ṣe tí wọ́n ń pè ní “Gateway to Nations”. June 5 sí June 7, 2015 ni wọ́n ṣayẹyẹ yìí. * Gbàrà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nílùú New York gbọ́ nípa ayẹyẹ tó fẹ́ wáyé yìí ni wọ́n ti ṣètò bí àwọn náà ṣe máa wà níbẹ̀. Kí nìdí?

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti tú àwọn ìwé tó ṣàlàyé Bíbélì sí onírúurú èdè, tó fi mọ́ àwọn èdè ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà bíi Blackfoot, Dakota, Hopi, Mohawk, Navajo, Odawa àti Plains Cree. Torí náà, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ síbi ayẹyẹ “Gateway to Nations,” wọ́n sì to àwọn tábìlì tó fani mọ́ra àtàwọn ìpàtẹ láti fi pàtẹ ìwé ìròyìn láwọn èdè yìí títí kan àṣàrò kúkúrú You Can Trust the Creator!

Àwọn ìtẹ̀jáde tá a gbohùn rẹ̀ sílẹ̀ àtàwọn fídíò tún wà lórí ìkànnì wa ní èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn èdè ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà tá a mẹ́nu kàn yìí. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbi ayẹyẹ náà fi àwọn fídíò yìí han àwọn tó wá wo ìpàtẹ wa. Àwọn tó wá wo àwọn fídíò náà sọ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì tàbí èdè Sípáníìṣì nìkan lọ̀pọ̀ àwọn tó kù ń lò níbi ìpàtẹ wọn, èdè yẹn lọ̀pọ̀ wọ́n sì fi ṣe gbogbo ohun tí wọ́n ṣe. Àfi bí wọ́n ṣe rí àwọn èdè ìbílẹ̀ wọn níbi ìpàtẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Bá a ṣe tú àwọn ìwé wa sí oríṣiríṣi èdè ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà ya ọ̀pọ̀ àwọn tó wá síbi ayẹyẹ náà lẹ́nu. Àmọ́, ohun tó wú wọn lórí jù ni bá a ṣe ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé-lóko. Lẹ́yìn tí ọkùnrin kan tó ń ṣiṣẹ́ níbi ayẹyẹ yìí wá mọ̀ nípa ohun tá à ń ṣe, ó sọ pé ká wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ní, “Mò ń wọ̀nà fún ìgbà tí ẹ máa wá sọ́dọ̀ mi, témi náà á sì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ láti inú Bíbélì!”

Àwọn tọkọtaya kan tí wọ́n jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà tí wọ́n sì tún jẹ́ odi yà sí ọ̀kan lára àwọn ìpàtẹ wa, àmọ́ Ẹlẹ́rìí tó wà níbẹ̀ ò gbọ́ èdè adití. Kò wá pẹ́ sígbà yẹn tí Ẹlẹ́rìí kan tó gbọ́ èdè adití fi dé. Nǹkan bí ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú ni arábìnrin wa yìí fi bá àwọn tọkọtaya tó jẹ́ odi náà sọ̀rọ̀, ó sì fi bí wọ́n á ṣe mọ ibi táwọn adití ti máa ṣe àpéjọ agbègbè àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ládùúgbò wọn hàn wọn.

Láàárín ọjọ́ mẹ́ta tí wọ́n fi ṣayẹyẹ yìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kópa nínú iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níbẹ̀ lé ní àádọ́ta [50], àwọn àlejò tó wá síbi ìpàtẹ wa sì gba àwọn ìwé tó lé ní àádọ́jọ [150].

^ ìpínrọ̀ 2 Ọ̀gbẹ́ni William K. Powers tó máa ń kíyè sí ìṣesí àwọn èèyàn ṣàlàyé bó ṣe máa ń rítáwọn ọmọ ìbílẹ̀ Amẹ́ríkà bá ń ṣe irú ayẹyẹ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí, ó ní, “ó jẹ́ ayẹyẹ táwọn èèyàn máa ń kọ́wọ́ tì, àwọn kan á máa kọrin, tọmọdé tàgbà lọ́kùnrin lóbìnrin tó wà níbẹ̀ á sì máa jó.” ​—Ìwé Ethnomusicology, September 1968, ojú ìwé 354.