MAY 23, 2018
ÍTÁLÌ
Ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò Ọ̀jọ̀gbọ́n Antonio D. Pinna, M.D.
Dókítà Pinna jẹ́ Ọ̀jọ̀gbọ́n nínú iṣẹ́ abẹ àti pípààrọ̀ ẹ̀yà ara ní University of Bologna, ní Ítálì. Ó tún jẹ́ ọ̀gá àgbà gbogbo àwọn tó ń ṣiṣẹ́ abẹ ní ẹ̀ka iṣẹ́ abẹ àti pípààrọ̀ ẹ̀yà ara ní Policlinico S. Orsola-Malpighi nílùú Bologna. Ó tún ń ṣiṣẹ́ ní Digestive Disease Institute tó wà ní Cleveland Clinic Abu Dhabi, níbi tó ti máa ń fi iṣẹ́ abẹ tọ́jú àrùn jẹjẹrẹ inú ẹ̀dọ̀, tó sì máa ń pààrọ̀ ẹ̀yà àra tó ti daṣẹ́ sílẹ̀.