Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 13, 2018
JAPAN

Ìjì Líle Jebi Jà ní Japan

Ìjì Líle Jebi Jà ní Japan

Ní Tuesday, September 4, 2018, ìjì líle kan jà ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Japan, ó ti lé lógún ọdún tírú ẹ̀ ti jà kẹ́yìn nílẹ̀ náà. Àwọn aláṣẹ ní kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ kúrò níbi tí wọ́n wà. Bó sì ṣe máa ń rí lọ́pọ̀ ìgbà, ohun tí ìjì líle náà bà jẹ́ kì í ṣe kékeré.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní Japan sọ pé kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ. Àmọ́ ó kéré tán, àwọn ará mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15) ló fara pa, ilé tó sì bà jẹ́ tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún àti méjìdínlógójì (538), ó kéré tán. Àyẹ̀wò àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe fi hàn pé Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́rìnlélógójì (44) ló bà jẹ́.

Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù, tó wà ní ìlú Osaka àti ní Sakai ti jọ ń ṣiṣẹ́ lórí bí wọ́n á ṣe ṣèrànlọ́wọ́, títí kan bí wọ́n á ṣe tún àwọn ilé tó bà jẹ́ ṣe, tí wọ́n á sì bẹ àwọn tọ́rọ̀ náà kàn wò.

A dúpẹ́ pé Jèhófà mọ ìṣòro tí àwọn ará wa ń ní, ó sì ń lo ẹgbẹ́ ará láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Sáàmù 34:19.