Jọ́jíà
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-èdè Georgia
-
Iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà—18,782
-
Iye àwọn ìjọ—224
-
Iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi—34,969
-
Iye èèyàn tí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan máa wàásù fún— 198
-
Iye èèyàn—3,689,000
Àkànṣe Àpéjọ Àkọ́kọ́ Tó Wáyé Nílùú Tbilisi, ní Jọ́jíà
Àpéjọ yìí jẹ́ àkọ́kọ́ irú ẹ̀ ní Jọ́jíà, ọ̀pọ̀ àsọyé tó ń gbéni ró, tó sì dá lórí Bíbélì ni wọ́n gbọ́ níbẹ̀, àwọn ará fìfẹ́ gba àwọn ará wọn lálejò, wọ́n sì ṣàfihàn àṣà ìbílẹ̀ wọn àti ìtàn ilẹ̀ wọn.
Orílẹ̀-èdè Jọ́jíà Gbà Pé Àwọn Jẹ̀bi Nílé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù (ECHR) sọ ìpinnu wọn pé àwọ́n ti gbọ́ ẹ̀bẹ̀ orílẹ̀-èdè Jọ́jíà nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́wàá.
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Yúróòpù Fọwọ́ sí I Pé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Lẹ́tọ̀ọ́ Láti Ṣe Ẹ̀sìn Wọn ní Jọ́jíà
Ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ ECHR dá lẹ́nu àìpẹ́ yìí jẹ́ káwọn Ẹlẹ́rìí lè pàdé pọ̀ láti jọ́sìn fàlàlà, kí wọ́n sì bá àwọn aládùúgbò wọn sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ láìsí wàhálà.